Mo ti ń làágùn gidi báyìí lórí ọ̀wọ́ngógó "diesel" tó bá Nàìjíríà - Obasanjo

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, Olusegun Obasanjo ti bu ẹnu àtẹ́ lu bí ọ̀wọ́n gógó ṣe ti dé bá dísù ní orílẹ̀ èdè yìí pàápàá bí ó ṣe ń ṣàkóbá fún fún ìpèsè ẹja.
Obasanko tí òun náà jẹ́ àgbẹ̀ tó ń pèsè ẹja ní ojoojúmọ̀ ni ọkàn òun kìí balẹ̀ nítorí bí àlékún ṣe ti ń bá owó d;ísù àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún ẹja jẹ.
Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ọ̀hún sọ̀rọ̀ yìí níbi àpérò àwọn àgbẹ̀ ẹlẹ́ja tó wáyé ní Abeokuta, olú ìlú ìpínlẹ̀ Ogun.
Ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbẹ̀ ẹlẹ́ja ní ó ṣeéṣe kí wọ́n fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí bí owó epo dísù ṣe ń lọ sókè lójoojúmọ́, tí oúnjẹ àwọn ẹja náà kò fi ìgbà kankan wálẹ̀ ń ṣe àkóbá fún ọrọ̀ ajé wọn.
Ó fi kun pé àyàfi tí àwọn àgbẹ̀ náà bá fi ìmọ̀ ṣọ̀kan, kí wọ́n pawọ́pọ̀ láti fẹnukò lórí iye kan gbòógì tí wọ́n ma máa ta ẹja wọn.
Ò ṣàláyé pé ẹgbẹ̀rín náírà tí lítà epo dísù kan ti dà lásìkò yìí ti sọ iye tí wọ́n fi ń sin ẹja kílógírààmù kan di ẹgbèje náírà àti pé àgbẹ̀ tó bá fẹ́ jèrè kò gbọdọ̀ dín owó tó bá ma tà á ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin náírà.
Obasanjo ní epo dísù gbówó lórí nítorí àwọn tó ń ṣe àkóso orílẹ̀ èdè yìí ti mẹ́hẹ.
Ó fi kun pé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí wọn kò bá tètè wá ojútùú sí gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí , gbogbo àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n ń lo dísù láti pèsè ẹja ma kógbá sílé.
“Ẹja ma wá di ọ̀wọ́n gógó tó jẹ́ wí pé láti ilẹ̀ òkèrè ni wọ́n ti ma ma kó ẹja wá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.”
“Èyí ma sọ àwọn ènìyàn di aláìníṣẹ́ tí òṣì yóò sì gba ìlú kan.”
Obasanjo wá pàrọwà sí àwọn àgbẹ̀ ẹlẹ́jà láti fìmọ̀ ṣọ̀kan kí ọ̀sìn ẹja le máa tẹ̀síwájú.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́ja lẹ́kùn ìwọ̀ oòrùn gúúsù Nàìjíríà, Amo Tunbosun ní mílíọ̀nù mẹ́ta lé ọwọ́ mẹ́fà ni ẹja tí Nàìjíríà ń jẹ lọ́dọọdún ṣùgbọ́n mílíọ̀nù kan lé ọwọ́ kan ni Nàìjíríà ń pèsè nínú rẹ̀.
Tunbosun ní lára ìpìníjà tó ń kojú ẹja sínsìn ni bí àwọn oúnjẹ ẹja ṣe ń wọ́n ní gbogbo ìgbà àti bí àwọn ènìyàn kìí ṣe fẹ́ ràá ní owó gege.















