Èèmọ̀ dé, Ṣé lóòtọ́ lọwọ́ Amotekun tẹ Ọmọ ọdún 18 tó ń bá abo ewúrẹ́ ní ìbálòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun?

Aworan Ewurẹ kan

Oríṣun àwòrán, other

Iroyin lati ipinlẹ Ogun n sọ pe ọwọ awọn agbofinro ikọ Amọtẹkun nibẹ ti tẹ arakunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan ti wọn ni ọwọ ba nibi to ti n ba abo ewurẹ ni ajọṣepọ.

Atẹjade kan ti adari agba ikọ Amọtẹkun ni ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni David Akinrẹmi fi sita ni eyi ti jẹyọ.

Wọn mu arakunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Ibrahim Ismaila nigba ti arakunrin kan to rii nibi ti o ti n hu iwa kayefi yii pariwo sita.

Agbegbe Ilu tuntun Olorunṣogo Ajọwa nijọba ibilẹ Ifọ ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.

Gẹgẹbi wọn ṣe sọ, arakunrin oṣiṣẹ ajorinmọrin kan lo n lọ si ibi iṣẹ to fẹ ṣe nibi ile tuntun kan ti wọn n kọ.

Nibi ile tuntun ti wọn n kọ yii lo ti ri ọdọmọkunrin naa to n ba abo ewurẹ ni ajọṣepọ.

Ariwo ti ọkunrin ajorinmọrin naa pa sita lo pe akiyesi awọn olugbe agbegbe naa ninu eyi ti oṣiṣẹ ikọ Amọtẹkun kan wa.