Olubadan flown abroad?: Ohun tí Ààfin sọ rèé lórí ipò àlàáfíà Olubadan

Agbelẹrọ ni iroyin ti ko lootọ ninu to n fo kaakiri lati ọwọ awọn ti o lerongba ti wọn lọkan nipa ipo alaafia Olubadan.
Bayi ni atẹjade taa ri ka lati ọdọ agbẹnusọ Olubadan, Oba Sen. Lekan Balogun, Alli Okunmade II, ti ṣe juwe iroyin to gbode pe wọn ti gbe Olubadan lọ gba itọju nilẹ okere.
Oladele Ogunsola to jẹ agbẹnusọ Olubadan sọ pe irọ lasan ati erongba aburu ẹni to kọ iroyin naa lo mu ko maa sọ pe wọn ti n gbe Olubadan kaakiri ile iwosan lẹnu ọjọ mẹta yi.
''Ki wọn to le sọ pe wọn n gbe eeyan digbadigba kaakiri ile iwosan, a jẹ pe wọ́n ri iru eeyan bẹẹ ni ile iwosan o kere tan bi ẹẹkan tabi lẹẹmeji lọsẹ ni. Mi o mọ ile iwosan ti akọsilẹ wa pe wọn gbe Olubadan lọ bọ sibẹ''
O fi kun un pe ''Oba Olubadan ti n ṣe gbogbo iṣẹ to yẹ ki ori ade maa ṣe lati igba to de ori alefa loṣu kẹta ọdun yi ati pe nibi ti ko sile lọ,awọn amugbalẹgbẹ ti n ṣe ojuṣe to yẹ''
Atẹjade yi tẹsiwaju pe ''toun ti pe awọn to gbe iroyin yi jade sọ pe eeyan kan lo sọ fun awọn l'aafin, ara ẹkọ iṣẹ iroyin ni pe ki wọn ṣe iwadii ọfintoto ki wọn to gbe iroyin jade. Ni paapa bi nkan ba ruju, pa a ti sẹgbẹ kan''.
Lafikun, agbẹnusọ Olubadan sọ pe ni ọjọ Ẹti to kọja ni Olubadan wa ni aaye ọwọ nii, Aliiwo nibi to ti ṣe agbega awọn oloye Iyalode ni ibamu pẹlu aṣa ilẹ Ibadan.
O parọwa sawọn akọroyin lati ri pe ohun ti wọn ba gbe jade jẹ ootọ ki wọn si ṣe iwadii lẹkunrẹrẹ.















