Ìwọ́ to ń gbé ìròyìn irọ́ pé mó ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀l'áwọn Òṣèré, wàá parẹ́ dànù! – Apostle Suleman

Apostle Suleman

Oríṣun àwòrán, Apostle Johnson suleman

Gbajugbaja oniwaasu ati adari ijọ Omega Fire Ministry, Apostle Johnson Suleman ti fi ibinu sọ oko ọrọ sita lori iroyin kan to ni oun gbọ nipa oun pe wọn fi ẹsun kan an pe o n ni ajọṣepọ pẹlu awọn oṣerebinrin lorilẹede Naijiria.

O ti pe ọjọ bii melo kan bayii ti iroyin naa n ja rayin-rayin lori ayelujara nigba ti gbajugbaja akọroyin sori ayelujara kan ti ẹni kankan ko mọ ẹni to wa labẹ ẹku eegun rẹ, Gistloverblog gbe akọsilẹ orukọ ọpọlọpọ awọn oṣerebinrin kan ni Naijiria ati nilẹ Afirika jade pe gbogbo wọn ni Oniwaasu Johnson Suleiman n ni ibalopọ pẹlu jade.

Lọrọ naa ba di boo lọ ya fun mi gẹgẹ bi awọn kan lara awọn obinrin naa ṣe bọ sori ayelujara wọn lati bu ẹnu atẹ lu iroyin rẹ pe iroyin ayederu ni awọn ko si ni ibalopọ pẹlu oniwaasu naa eyi ti o fi sita lọjọ Kẹrindinlọgbọn Oṣu Keje.

Atẹjade

Oríṣun àwòrán, gistlovergram_media

Awọn mii lara wọn ni lootọ awọn maa n lọ si ṣọọṣi rẹ bẹẹ si ni oju to mọ ni ko le ni oun kọ mọ eeyan mọ. Wọn ni awọn ko le ṣẹẹ pe awọn ko mọ Apostle Suleiman ri toripe eeyan daradara ni awọn ko si ni parọ tori pe oniroyin kan n gbe iroyin ofege kiri ilu.

Ẹwẹ, lẹyin ọjọ ti orukọ awọn oṣere ti akọroyin ori ayelujara yii fi sita bẹrẹ si ni di ariwo lẹnu awọn eeyan ni Oluṣọ ijọ Omega ti a ko gburoo ko da si ọrọ naa tẹlẹ dede fi fidio kan sita loju opo ayelujara rẹ.

Bakan naa ni akọroyin ọhun tun fi ẹsun kan pe Apostle Suleman n tẹ igbagbọ rẹ nidi pẹlu oogun ibilẹ.

Suleman nigba to fesi ninu fidio to fi sita sọ pe “ẹ mọ pe oju mi di pẹlu awọn isọji itagbangba ti mo n ṣe, mo wa gbọ pe wọn n wọ mi lori ayelujara, wọn si ni ẹni naa n lo oogun, oogun naa ni yoo pa ọ”.

Oniwaasu suleman tun sọ pe oun ati ẹni naa yoo jọ wọ ara awọn ni. “Gbogbo awọn ti wọn ni mo mọ yii, lara wọn jẹ awọn to ti wa si Ṣọọṣi mi, ṣe ki n wa ni mi o mọ awọn ọmọ mi mọ tori pe iwọ n kọ kin kan?”

"Orukọ too kọ sita ko gun to, kuku sọọ di 200"

Apostle Johnson Suleman

Oríṣun àwòrán, Apostle Johnson Suleman

Suleman ni orukọ to kọ sita ko tii gun to, ko kuku sọọ iye wọn di igba.

Bakan naa ni Oniwaasun naa sọ pe bi akọroyin ọhun ba dawọ duro, ajẹ pe ko mọ nkan ti o n ṣe tori odidi iran kan lo rawọ le pe o fẹ wọdi rẹ lori ayelujara.

“Emi ni maa pa oju opo “bulọọgi” yẹn rẹ pata pata, o ti ko si panpẹ mi”.

O fi kun un pe nigba ti oun ri iye orukọ awọn ti o kọ sita, oun kan n bu si ẹrin ni.

Apostle suleman wa ni akọroyin ori ayelujara ọhun to da bii eegun ti ko sẹni to mọ oju rẹ wa fi ara rẹ han bi o ba da ara rẹ loju ati pe ko fi adirẹsi ile rẹ sita ki awọn wa ba a.

O wa fi fido rẹ tun gba awọn eeyan nimọran pe ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni ko wọn laya jẹ.

O tun ni ki wọn ma san owo fun awọn abatẹnijẹ, ki wọ́n jẹ ki wọn kọ ohun to ba wu wọ́n.

Kí ni esi Akọroyin Gistlover lẹyin fidio Apostle Suleman?

Oju ẹni ti ẹ ko mọ

Oríṣun àwòrán, gistlovergram_media

Ẹwẹ, lẹyin ikilọ yii, bo tilẹ jẹ pe Apostle Suleman ko darukọ akọroyin to n ba wi ni akọroyin ori ayelujara Gistloverblog tun ti n fi awọn atẹjade sita nipa Oniwaasu naa to si ni afi laa, oun ko ni dawọ duro afi ti oun ba tu iṣu de isalẹ koko ati gbogbo aṣiri ti oun n ri nipa Apostle Johnson Suleman.

Gistlover naa tun ni oun mọ nkan ti oun n sọ, ti oun naa si n fi oko ọrọ ranṣẹ pada si Apostle.