Johnson Sulemann sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn tí Stephanie Otobo fi kàn án

Suleman ati Otobo

Oríṣun àwòrán, @Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Alufaa agba ijọ Omega Fire Ministries, Apostle Johnson Suleman ti sọrọ lẹyin ti olorin takasufe to n fi ilu Canada ṣe ibugbe, Stehanie Otobo, halẹ mọ loju opo Twitter pe oun yoo fi fidio ibalopọ awọn mejeji lede.

Ṣaaju ni Otobo ti kọkọ fẹsun kan alufaa naa pe awọn n ni ibalopọ fun ọdun mẹrin gbako ki aarin awọn mejeji to daru.

Ẹnu ọjọ mẹta yii Otobo tun fi aworan ihoho kan lede loju opo Twitter rẹ, to si n sọ pe aworan ihoho ti Suleman fi sọwọ si oun ni, ati pe ko wa sọ boya awọn aworan naa kii ṣe tirẹ.

Ọdun 2017 ni iroyin ibaṣepọ Otobo ati Suleman kọkọ gbode, lẹyin ti Otobo pe Suleman lẹjọ lori ẹsun fifi ọwọ kan oun lọna aitọ.

Lara awọn aworan ti Otobo fi lede loju opo Twitter ṣafihan bi okunrin kan ṣe di nnkan ọmọkunri rẹ mu, eyii to pe ni ti Suleman amọ a ko le fidi rẹ mulẹ boya ti Suleman ni tabi bẹẹ kọ.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Aworan mii ṣafihan ibi ti Otobo ti gbe ọmu rẹ jade lori ipe ori fidio, eyii to ni oun ati Suleman lo n sọrọ lasiko naa.

Àkọlé fídíò, Agbẹjọ́rò Abdullateef Lanre Abdullahi sọ pàtàkì ìbálòpọ̀ àti ìmọ́tótó láàrin lọ́kọláya

Otobo ni "To ba parọ pe nnkan ọmọkunrin naa kii ṣe ti oun, ki ni yoo sọ nipa apa to wa ni itan apa osi rẹ? Iyawo rẹ gan ko le sẹ pe ko ni apa ni itan rẹ."

"Ti n ko ba ni nnkan ṣe pẹlu rẹ, bawo ni mo ṣe mọ pe o ni apa ni itan rẹ?"

Àkọlé fídíò, 'Mo fara da ìsòro gan láwùjọ́ torí àwọn òbí mi di létí'

Obinrin naa ni Alufaa Suleman ti dukoko mọ oun lọpọ igba, koda o gbiyanju lati gbẹmi oun pẹlu.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Johnson Suleman fesi

Ẹwẹ, lasiko to n fesi si ọrọ naa loju opo Twitter, alufaa Johnson Suleman sọ pe awọn ọta oun lo n lo Otobo lodi si oun lẹyin ti oun sọrọ tako ijọba Naijiria lori iyanṣẹlodi ẹgbẹ awọn olukọ fasiti, ASUU.

Àkọlé fídíò, Osun spider man: Mo ń ṣe ìtanijí láti gbógunti ìdọ̀tí láwùjọ ló sún mi dé ìdí 'Spider man'

O ni "Ni kete ti mo sọ pe ki ijọba fopin si iyanṣẹlodi ASUU lana ọjọ Aiku ati oni ọjọ Aje, ni ọrọ mi gbode loju opo Twitter."

"Odaa o, amọ iba daa ki ẹ fi akoko diẹ si aarin ọrọ ti mo sọ ki ẹ to maa jẹ ọrọ mi lẹnu lori Twitter ko le sọro lati mọ pe ọrọ ti mo sọ lo jẹ ki ẹ maa jẹ ọrọ mi lẹnu. Ẹ fi opin si iyanṣẹlodi ASUU!"

Àkọlé fídíò, Babalawo, Ọ̀pẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi ń yan Ọba fún wa, kí ló dé tẹ́ẹ fẹ́ wo owó yan Soun fún wa? - Ọmọ ìdílé òyè l'Ogbomoso