Chrisland Student Sex Video: Olùkọ́ mẹ́rin fojú balé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀

Chrisland

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Awọn olukọ mẹrin nile ẹkọ Chrisland Schools to ba awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa lọ siluu Dubai fun eto World School Games ti foju bale ẹjọ majisttreeti to wa ni Yaba, niluu Eko.

Orukọ awọn olukọ naa ni Oladotun Sotunde, Elesho Tajudeen, Rhoda Olanipekun ati Ajiboye Hammed.

Awọn eeyan naa n koju ẹsun igbimọpọ lati da omi alaafia ilu ru, eyii ti ileeṣẹ ọlọpaa fi kan wọn.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ti kọkọ paṣẹ ki wọn gbe gbogbo ẹka ile ẹkọ Christland College to wa l'Eko ti pa lẹyin ti fidio ibalopọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ naa ni Duabai fa oju opo Twitter ya.

Amọ ijọba ṣi ile ẹkọ naa pada lẹyin iwadii iṣẹlẹ ọhun.

Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ Uche Igwe di èrò iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pínpín fídíò ìbálòpọ̀ ọmọdé

Chrisland

Oríṣun àwòrán, Others

Magisreti Adeola Adedayo wa gba beeli rẹ ni iye owo to to miliọnu mẹwaa Naira ati oniduro mẹta.

Sọrọsọrọ Uche Igwe ti yọju si ileẹjọ lori ẹsun pe o ṣe atunpin fidio ibalopọ ọmọ ọdun mẹwaa lori ẹrọ ikansiraẹni, Twitter.

Fidio ọmọ ọdun mẹwa ni ileẹkọ Chrisland ni agbegbe Lekki, nipinlẹ Eko to n ba akẹgbẹ rẹ ni ibalọpọ ni sọrọsọrọ naa ṣe atunpin rẹ lori ẹrọ Twitter.

Igwe to n gbe ni agbegbe Ikorodu nipinlẹ Eko ni ileẹjọ fi ẹsun oniga meji kan.

Ẹsun naa ni titẹ oju ofin to de alaafia ilu mọlẹ ati idunkokomọni lori ayelujara.

Agbẹjoro fun ijọba ni ileeṣẹ ọlọpaa ni Panti, nipinlẹ Eko, Augustine Nwabuisi ni Igwe ṣe atunpin fidio naa pẹlu imọ rẹ ni kii ṣe aṣiṣe.

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Ẹsun onigun meji ni ijọba fi kan an

Igwe lo oju opo Twitter rẹ gangan lati pin fidio naa kaakiri ẹrọ ayelujara lai gba aṣẹ ileẹkọ tabi lọwọ obi awọn ọmọ naa.

Ijọba ni Ọjọ Kejidinlogun, Oṣu Kẹrin, ọdun 2022 ni sọrọsọrọ naa ṣe aṣemaṣe ọhun.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Ihuwasi naa tako ofin ipinlẹ Eko to de ihuwasi awọn eniyan lori ẹrọ ayelujara ati iwa ọdaran ni ipinlẹ Eko.

Amọ sọrọsọrọ naa ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

Magisreti Adeola Adedayo wa gba beeli rẹ ni iye owo to to miliọnu mẹwa Naira ati oniduro mẹta.

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'