Goodluck Jonathan: Ẹgbẹ́ PDP àti APC sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn pé Jonathan ti lọ sí ẹgbẹ́ APC

Goodluck Jonathan

Oríṣun àwòrán, GOODLUCK JONATHAN / FACEBOOK

Ariyanjiyan ṣi n waye lori iroyin pe aarẹ Naijiria tẹlẹ, Goodluck Jonathan, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC.

Ọjọ Aje ni iroyin naa jade, pẹlu afikun pe ẹgbẹ awọn fulani darandaran ti ra fọọmu fun lati dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC.

Bo tilẹ jẹ pe Jonathan funra rẹ ti kede pe oun ko ran ẹnikẹni niṣẹ lati ra fọọmu fun oun.

Ninu atẹjade kan to fi sita, agbẹnusọ fun aarẹ tẹlẹ naa, Ikechukwu Eze ni Jonathan kọ ẹbun naa jalẹ.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ oṣelu APC, Felix Morka sọ fun BBC pe oun ko ni le fidi iroyin naa mulẹ pe lootọ ni Jonathan ti wa si APC.

Àkọlé fídíò, Iyabo Anisulowo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ Nàìjíríà, ẹ má bínú, kò rọrùn fún ọ̀dọ́ láti dìde nínú ìṣèlú

Lori pe boya o ṣe e ṣe fun ẹni ti kii sẹ ọmọ ẹgbẹ APC lati ra fọọmu oludije, Ọgbẹni Morka sọ pe "awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC nikan lo ni ẹtọ lati ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo.

"Lootọ ni ẹgbẹ tabi ẹnikẹni le ra fọọmu, ṣugbọn nibi eto ayẹwo ti yoo waye fun gbogbo wọn ni iwadii yoo ti fihan boya ọmọ ẹgbẹ ni onitọhun, imọ eto ẹkọ to ni, iye asiko to ti wa ninu ẹgbẹ.

"Awọn nkan wọnyii si ni yoo sọ boya wọn o fun ni tikẹẹti lati ṣoju ẹgbẹ ninu eto idibo."

Àkọlé fídíò, Adewole Quyum: Ọdún10 ni mo ti ń kọ́ 'welder' mo ti ṣe ọ̀kadà tó ń lo 'generator'

Jonathan ko tii sọ boya o ti kuro ni PDP lọ si APC - PDP

Lori ọrọ yii kan naa, agbẹnusọ ẹgbẹ osẹlu Peoples Democratic Party, PDP, Debo Ologunagba, sọ pe oun ko le gbẹnusọ fun Goodluck Jonathan.

"Oun ni yoo fi ẹnu ara rẹ sọ boya o ti kuro ninu ẹgbẹ PDP.

"O ti sọrọ pe oun ko ran ẹnikẹni lati gba fọọmu ẹgbẹ osẹlu APC fun oun. Nitori naa, ko si nkan mii ti mo tun fẹ sọ mọ."

Àkọlé fídíò, Ó yẹ kí a wádìí ikú tó pa Oba Lamidi Adeyemi, Baba gbọ́dọ̀ padà- Sat Guru Maharaj-ji

Mi ò rán Miyetti Allah níṣẹ́ láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC fún mi - Jonathan

Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Goodluck Jonathan ti kede rẹ sita lohun goorogo pe oun ko nifẹ si didje fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, nitori naa oun ti kọ fọọmu idije ti ẹgbẹ awọn fulani, Miyetti Allah ra lorukọ oun.

Ni ọjọ Aje ni ẹgbẹ Miyetti Allah kede pe awọn ti ra fọọmu idije ọlọgọrun miliọnu Naira lorukọ Goodluck Jonathan lati dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Jonathan

Oríṣun àwòrán, Others

Amọṣa, aarẹ ana, Goodluck Jonathan ti ni ohun ko ran ẹnikẹni niṣẹ lati lọ ree ra fọọmu idije fun oun.

"O ti wa si eti igbọ wa pe pe awọn ẹgbẹ kan ti lọ ra fọọmu idije lẹgbẹ oṣelu APC lorukọ aarẹ tẹlẹ, Ọmọwe Goodluck Ebele Jonathan."

"A fẹ laa ko yeawọn eeyan pe bi aarẹ tẹlẹ naa ba fẹ dije fun ipo ibo kankan, yoo mu erongba rẹ han ni gbangba, kii ṣe ni kọọrọ"