WAEC 2022: Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara tí yóò ṣe ìdánwò WASSCE lọ́dún 2022

Oríṣun àwòrán, other
Ajọ to n ṣeto idanwo aṣekagba girama lẹkun iwọ oorun Afirika, WAEC ti fidi rẹ mulẹ pe ko si akẹkọọ ile ẹkọ ijọba kankan nipinlẹ Sokoto ati Zamfara ti yoo kopa ninu idanwo aṣekagba girama tọdun 2022.
Adari ajọ WAEC lorilẹede Naijiria, Patrick Areghan lọ sọ eyi di mimọ ninu ifọrọwerọ kan pẹlu awọn akọroyin.
- Báwo ni ọ̀rọ̀ ilé ṣe fa Gbas-gbos láàrín Mercy Aigbe, ìyáále rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀?
- Kọ́ńdọ̀ọ̀mù méjìlá lá rí ní iyàrá ilé ìtura tí wọ́n ti fípa bá arábìnrin Ulochi lòpọ̀- Olọ́pàá
- Èmi ò gbé'ṣẹ́ rán ẹnikẹ́ni láti ra fọ́ọ̀mù ìdíje ààrẹ fún mi o, ẹ máà kóbá mi -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ Goodluck Jonathan fún Miyetti Allah lésì
- Wo àwọn òjé tí àwọn olóṣèlú máa fi ń jẹ àwọn ènìyàn bí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́lé
O ni idanwo naa yoo waye laarin ọjọ kẹrindinlogun oṣu karun un si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹfa ọdun 2022.
Amọṣa gbogbo akitiyan lati bi adari ajọ naa leere ohun to fa eyi lo ja si pabo pẹlu bo ṣe ni oun ko lọrọ kankan lati sọ nipa ohun to ṣokunfa rẹ.
Areghan ni miliọnu kan ati ẹgbẹta akẹkọọ ni yoo ṣedanwo naa lọdun 2022 lati ẹgbẹrun lọna ogun ati okoolelugba ati ẹyọkan ileẹkọ kaakiri orilẹede Naijiria.
Ajọ naa ni awọn ko ni fi aye gba iwa aitọ yoowu lasiko idanwo naa.










