2023 Election: Yahaya Bello ti ra fọ́ọ̀mù N100m láti díje dupò ààrẹ APC

Yahaya Bello

Oríṣun àwòrán, Yaya Bello/ twitter

Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti san ọgọrun miliọnu naira lati fi ra fọọmu ti yoo fi dije dupo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2023.

Owurọ Ọjọ Iṣẹgun ni Gomina naa ra fọọmu naa, eleyii to sọ di ẹni akọkọ ti yoo kọkọ ra fọọmu oludije ipo aarẹ ni ẹgbẹ oṣelu APC.

Adari ipolongo fun idije dupo aarẹ Yahaya Bello, Yemi Kolapo lo fi atẹjade naa sita lẹyin ti gomina naa kede ni Ọjọ Keji, Oṣu Kẹrin pe oun yoo dije du ipo aarẹ ni ọdun 2023.

Bio tilẹ jẹpe gbungun orilẹede Naijiria lo ti wa, ti awọn eniyan si n lọgun fun ipo aarẹ ni Guusu Naijiria.

Ninu atẹjade ti wọn fi lede ni wọn ti sọ wi pe ki awọn ololufẹ gomina naa fi ọkan balẹ nitori orukọ rẹ yoo wa ninu awọn oludije ni ọdun 2023.

Bakan naa ni wọn fikun un pe Yahaya Bello jẹ eniyan ti wọn pe o ṣe e gbẹkẹle ni gbogbo ọna.

Gomina Yahaya Bello naa wa rọ awọn ololufẹ rẹ lati dibo yan an ki ohun gbogbo to ni lọkan fun awọn ọmọ Naijiria le wa si imuṣẹ.