Power Cable Kills Children in Ondo: Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Wáyà iná ọba

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ti ní àwọn ọmọdé mẹ́rin ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá wáyà iná tó já lé àwọn ọmọ náà lórí ní Ilé Oluji, ìjọba ìbílẹ̀ Okeigbo, ìpínlẹ̀ Ondo.

Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo, Funmilayo Odunlami, ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n, oṣù kẹrin ọdún 2022 sọ pé àwọn ọmọdé náà ṣe kòńgẹ́ ọlọ́jọ́ wọn nígbà tí wáyà iná ọba já lé ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n fi irin ṣe kan èyí tí àwọn ọmọ náà wà.

Odunlami ṣàlàyé pé àwọn méjì nínú àwọn ọmọ mẹ́rin tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ló jẹ́ ọmọ ìyá kan náà tó lọ sí ìlú náà fún ìsinmi ọdún àjíǹde.

Ó fi kun pé àwọn ọmọ mẹ́fà ló ń ṣeré nínú ṣọ́ọ̀bù náà kí wáyà iná ọba tó já lulẹ̀ tí àwọn mẹ́rin sì bá ìsẹ̀lẹ̀ náà lọ nítorí kò sí afẹ́fẹ́ èémí tí wọn yóò ló fún wọn ní ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé wọn lọ.

Ó sọ síwájú pé ọ̀kan nínú àwọn ọmọ méjì tó kù ni ara rẹ̀ ti balẹ̀ lẹ́yìn tó gba ìtọ́jú ní Trauma Centre tó sì ti padà sí ilé, tí ọ̀kan yòókù sì wà ní ilé ìwòsàn O.A.U níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́.

Odunlami ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Àwọn ènìyàn korò ojú sí kíkọ́ ilé sábẹ́ wáyà iná

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣojú ẹkùn gúùsù Ondo ní ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àpapọ̀ ní Abuja, Nicholas Tofowomo ni òun yóò ṣe àrídájú rẹ̀ wí pé àwọn òbí ọmọ tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ láti rí ìdájọ́ òdodo gbà tí ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ̀nà Benin bá lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Tofowomo rọ àwọn ènìyàn láti yé kọ́ ilé tàbí ṣọ́ọ̀bù sábẹ́ àwọn wáyà iná èyí tó le ṣe àkóbá fún wọn.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ náà dùn wá púpọ̀ - ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná

Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Ondo, Micheal Barnabas ní ìdí tí ìjàmbá náà ni pé abẹ́ wáyà iná tó lágbára ni àwọn ṣọ́ọ̀bù náà wà.

Barnabas ní ó jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́ wí pé àwọn ògo wẹẹrẹ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ sí tó sì ṣeni láàánú.

Àkọlé fídíò, Kò sí ńkan ti ọkùnrin ń ṣe tí obìnrin kò le ṣe- Afusat Adeniyi tó ń tún 'Pumping Machine'

Ó fi kun wí pé àwọn kò ní àṣẹ láti lé ẹnikẹ́ni tó bá kọ́lé tàbí tàbí ní ilé ìtajà lábẹ́ àwọn wáyà iná kúrò.

Ó sọ síwájú wí pé ohun tí àwọn yóò máa ṣe báyìí ni láti ri pé àwọn kò fún ilé tàbí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n bá kọ́ sábẹ́ àwọn wáyà ní iná láti fi hàn wọ́n wí pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dára.