World Malaria Day 2022: Wo àwọn nkan ti o lé ṣe láti dáàbò bo ara rẹ lọ́wọ́ oró àìsàn ibà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni a ṣe le da ibà duro?
Bo tilẹjẹ wi pe aisan yii jẹ ohun to ṣe e dena, to si ni itọju, o ṣi n ṣeku pa ọpọlọpọ. Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ eto ilera ni agbaye, WHO, aisan iba n ṣeku pa ọmọde ni iṣẹju meji-meji, eniyan to le ni igba miliọnu si ni akọsilẹ wa pe o n ni aisan yii l'ọdun.
Lootọ ni igbogun ti ibà ti lọ soke sii daada lati bi ọdun mẹwaa, ṣugbọn ọ̀rọ̀ naa tun ti kọja agbara lati ọdun 2015: Abọ iwadi ajọ WHO nipa aisan ibà l'agbaye, to fi sita l'ọdun 2018 fihan pe ko fi bẹẹ si adinku ninu iye awọn to ni aisan ibà laarin ọdun 2015 si 2017.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu kẹrin ṣe wa a jẹ Ayajọ aisan iba l'agbaye, awọn nkan to yẹ ki o mọ nipa aisan naa ni yii.
- Ibà jẹ aisan to maa n dunkoko mọ ẹ̀mí, eyi ti kokoro aifojuri mẹrin n fa: P. falciparum, P. malariae, P. ovale ati P. vivax.
- Awọn kokoro aifojuri yii maa n wọ ara eniyan lasiko ti abo ẹ̀fọn ti wọn tun maa n pe ni ''olokoowo iba'' ba jẹ eniyan.
- Aisan ibà ṣe e dena, o si ṣe e tọju.
- L'ọdun 2017, awọn eniyan to to okoolerugba din ẹyọkan lo ni ibà ni orilẹede mẹtadinlaadọrun (Akọsilẹ ajọ WHO)
- Eniyan to to ojilenirinwo din maarun, 435,000, ni ibà pa l'ọdun 2017
- Ilẹ Afirika ni aisan ibà pọ si ju - l'ọdun 2017 nikan, ìdá mejilelaadọrun ni awọ̀n to tni ibà ni Afirika, ìdá mẹtalelaadọrun si lo pa.
- Apapọ owo ti wọn naa lati fi gbogun ti ibà le biliọnu mẹta Dọla ( $3.1bn) ni 2017.
Awọn apẹẹrẹ ibà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn apẹẹrẹ ibà - ara gbigbona, ori fifọ, ati otutu - eyi to maa n fi ara han laarin ọjọ mẹwaa si mẹẹdogun ti ẹ̀fọn to n pin ibà ba jẹ ni
Awọn apẹẹrẹ naa le ma han pupọ, ṣugbọn ti ko ba si itọju laarin wakati mẹrinlelogun, ibà ti kokoro aifojuri 'P. falciparum' ba fa le yọri aisan to n pani.
Taa lo wa ninu ewu?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
L'ọdun 2017, bi ilaji awọn to wa ni aye lo wa ninu ewu nini aisan iba.
Awọn ọmọde ti ọjọ ori wọn ko to ọdun maarun lo wa ninu ewu ju: L'ọdun 2017, awọn lo ko ìdá mọkanlelọgọta(266,000) ninu awọn ti ibà pa l'agbaye.
Awọn to tun wa ninu ewu to l'agbara ni awọn alaboyun, ati awọn ti agọ-ara wọn ko l'agbara to lati gbogun ti aisan.
Awọn agbegbe wo lo wọpọ si ju?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, ọpọ̀ aisan iba ati iku to waye nipa a rẹ n ṣẹlẹ ni agbgbe ilẹ olooru Afirika, ṣugbọn awọn agbegbe kan ni South-East Asia, Eastern Mediterranean, Western Pacific, ati nilẹ America naa wa ninu ewu.
L'ọdun 2017, orilẹede maarun lo fẹ ẹ ko ilaji ninu awọn to ni ibà kaakiri agbaye: Nigeria (25%), Democratic Republic of the Congo (11%), Mozambique (5%), India (4%) ati Uganda (4%).
Bi aisan ibà ṣe n wọ inu ara

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni ọpọ igba, aisan iba maa n wọ ara ti abo ẹ̀fọn (Female Anopheles) ba jẹ eniyan - oriṣi abo ẹ̀fọ̀n to wa le ni irinwo, ninu eyi ti bi ọgbọ̀n jẹ 'olokoowo iba' to jẹ pataki.
Laarin irọlẹ si idaji si ni gbogbo awọ̀n olokoowo pataki yii maa n jẹ eniyan.
Inu omi ni abo ẹ̀fọ̀n yoo ye ẹyin rẹ si, eyi ti yoo dagba di ẹ̀fọn; abo ẹ̀fọn maa n wa ẹ̀jẹ̀ lati fi bọ́ awọn ẹyin wọn.
Ọna lati dena iba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ WHO la awọn ọna abayọ to n ṣiṣẹ silẹ fun gbogbo eniyan to wa ninu ewu nini aisan iba.
Oriṣi ọna meji - àpò to ni oogun apẹfọn ati fi fi oogun apẹfọn fin inu ile - mejeeji maa n ṣiṣẹ daada l'oriṣiriṣi igba
Sisun si abẹ apo apẹfọn le mu adinku ba ifarakanra laarin ẹ̀fọn ati eniyan nipa pipese idiwọ to ṣe e fi oju ri ati oogun to le kapa kokoro.
Lilo oogun apẹfọn jẹ fi fi iru oogun bẹ fin ile lẹẹkan tabi ẹẹmeji l'ọdun.
A tun le dena aisan iba nipa lilo awọn oogun to le gbogun ti iba fun awọ̀n arinrinajo, alaboyun, awọn obinrin ati awọn ọmọde.
Ayẹwo ati itọju aisan iba
Early diagnosis and treatment yields best results T

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aisan iba ṣe e tọju - ayẹwo le ṣe afihan aisan iba ninu ara laarin ọgbọ̀n iṣẹju tabi ko maa to bẹ.
Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, ti tete ṣe ayẹwo ati itọju fun aisan ibà maa k'apa rẹ, o si tun maa n dena iku ati itankalẹ aisan iba.
Itọju to dara ju to wa fun un, paapa fun aisan ibà ti kokoro aifojuri P. falciparum ba fa, ni ' artemisinin-based combination therapy (ACT).'
Ibà ti agbara oogun apakokoro ati egboogi ko ka

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ WHO ti fi ikil sita pe abo ẹ̀fọn ti n fi agbara han lera-lera pe agbara egboogi ati oogun apakokoro ko ka oun - to si n mu idiwọ ba iṣẹgun lori iba.
Ibẹru to wa ni pe o ṣeeṣe ki awọn irinṣẹ idena ati amojuto to wa bayii le dawọ iṣẹ duro.
Akọsilẹ tuntun nipa aisan ibà l'agbaye fihan pe orilẹede mejidinlaadọrin lo jábọ̀ pe agbara oogun apẹfọn ko ka ẹfọn l'awọn akoko kan laarin ọdun 2010 si 2017.
Bakan naa ni iba ti agbara eegbogi ko ka naa n waye ni gbogbo igba.
Ajọ WHO sọ pe egboogi to n dena iba ṣe koko fun amojuto ati iparun aisan naa - o si n polongo ṣiṣe titọ pinpin ni awọn orilẹede ti ibà ti wọpọ ju.
Afojusun ni lati ri i daju pe wọn tete ri ibà ti agbara egboogi ko ba ka, ki wọn si kọju ija si ni kiakia ati l'ọna to yẹ.












