Osinbajo 2023: Ìyànjẹ ni fún ọmọ Naijiria tí mo bá fẹ̀yìntì báyìí- Osinbajo

Yemi Osinbajo

Oríṣun àwòrán, @Yemi Osinbajo

Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti sọ pe iwa ọdalẹ ati iyanjẹ ni yoo jẹ, ti oun ba fi kọ̀ lati dije fun ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023.

Awọn iwe iroyin abẹle sọ pe igbakeji aarẹ sọ ọrọ naa lasiko to bẹ gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ati awọn agba ẹgbẹ osẹlu APC wo nilu akurẹ, lọjọ Aje.

Nibẹ ni Osinbajo ti sọ erongba rẹ fun wọn pe, oun fẹ atilẹyin wọn fun ipo aarẹ.

Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC

Oríṣun àwòrán, laolu akande

Àkọlé àwòrán, Igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo, gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC

Ọjọgbọn Osinbajo sọ pe oun ko fẹ ki anfaani na fo oun ru, ati pe o jẹ oore-ọfẹ lati sin ilu.

"Mo pinnu lati dije fun ipo aarẹ, nitori iriri ti mo ni gẹgẹ bi adele aarẹ fun oṣu meje, iṣẹ kekere kọ ni mo ṣe nigba naa."

"Ni bayii ti anfaani ṣi silẹ fun mi, ati awọn eeyan ti mo mọ kakiri agbaye, iwa ọdalẹ ni yoo jẹ́ fun Naijiria, ti mo ba kọ lati sin orilẹ-ede yii."

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Osinbajo sọ pe ojoojumọ ni awọn eeyan n fi ẹmi wọn lelẹ fun Naijiria, nitoyi naa ni ko ṣe bojumu fun oun lati fẹhinti bayii fun igbadun, lai dupo aarẹ.

Lowurọ ọjọ Aje, ọjọ kọkanla ọdun 2022, ni igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo kede erongba rẹ lati dije fun ipo aarẹ, fun gbogbo aye.

Àkọlé fídíò, Ọdún 20 ni ìran ti jáde pé kí n di ààrẹ!'Wàláhì láàrín ọdún kan péré tí mo bá dé Aso Rock, ẹ wo ǹkan tí ...'

Awọn oloṣelu wo lo ti fi erongba ati dije ipo aarẹ Naijiria lọdun 2023 han?

Bola Ahmed Tinubu:

Bọla Tinubu jẹ ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ oṣelu APC, ohun si ni gomina ipinlẹ Eko laarin ọdun 199 si 2007.

Rochas Okorocha:

Okorocha ni gomina ipinlẹ Imo tẹlẹ, igba akọkọ rẹ si kọ niyi lati dije, lẹyin to ti kọkọ gbe igba ibo fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu AA nigba kan ri.

Rochas Okorocha fi erongba rẹ lati dije han ninu lẹta kan to kọ ranṣẹ si aarẹ ile aṣofin agba, Sẹnetọ Ahmad Lawan lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kini ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Khadija Okunnu -Lamidi:

Oun ni obinrin akọkọ to jade lati kede pe oun fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023. Ko tii kede ẹgbẹ oṣelu kankan ti o wa bayii na. Ohun to sọ ni pe ẹgbẹ oṣelu to ba ni iran kan naa pẹlu oun loun yoo ba lọ.

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

Dele Momodu:

loṣu kẹta ọdun 2023 ni Dele Mọmọdu kede pe oun naa yoo dije ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP.

Igba akọkọ kọ niyi ti Dele Mọmọdu yoo maa fifẹhan si didije fun ipo aarẹ ni Naijiria.

Yahaya Bello:

Yahaya Bello ni gomina ipinlẹ Kogi lọwọ yii. Laipẹ yii loun pẹlu kede pe oun naa nifẹ si ipo aarẹ lọdun 2023.

Awọn miran to tun ti gbe igbesẹ yii kan naa ni aarẹ ile aṣofin agba tẹlẹ ri, Dokita Bukọla Saraki, alaga igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijiria, NGF to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi, minisita fọrọ oṣiṣẹ ati igbanisiṣẹ, Dokita Chris Ngige ati bẹẹ lọ.

Àkọlé fídíò, Alfa Sule: Ọmọdé tí mò kọ́ ní lẹ́sìnì ló fún mi ní ìmísí àgbékalẹ̀ eré oníjó