Youths attack police station in ondo: Ọlọ́pàá kọ́ ló pa baálẹ̀ àtàwọn méjì tó kú ní Kajola, wọ́n ṣoríkunkun sí òfin ìrìnna ni - Ọlọ́pàá Ondo

Awọn ọdọ to sẹ iwọde lọ si agọ ọlọpaa Kajola

Oríṣun àwòrán, Tvc news

Àkọlé àwòrán, Awọn ọdọ naa yabo olu ileeṣẹ ọlọpaa nili Kajola, ti wọn si sọ pe awọn ko fẹ ọlọpaa kankan ni agbegbe awọn mọ

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti ṣalaye pe awọn oṣiṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa kọ lo ṣekupa awọn eeyan mẹta kan to ku nilu Kajọla, lagbegbe ijọba ibilẹ Odigbo .

Baalẹ ileto kan wa lara awọn eeyan to ṣalaisi naa lẹyin ti ọkọ kan kọlu wọn lagbegbe Kajọla loju popona marosẹ Eko si Ọrẹ nirọlẹ ọjọ Satide.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayọ Ọdunlami ASP ṣalaye fun BBC News Yoruba pe kii ṣe iwa familete n tutọ awọn ọlọpaa rara, bikoṣe titapa si ofin irinna oju popo.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo naa ṣalaye siwaju sii pe ọkada ti awọn oloogbe naa lo ko ni ina, wọn tun wa lọ n doju kọ ọna ọkọ to n bọ dipo ọna tiwọn eyi to mu ki wọn lọ kọlu ọkọ to n sare bọ loju ọna naa.

"Awọn ọlọpaa kọ lo pa wọn o, ṣe ni wọn tapa si ofin irinna loju popo.'

O ni awọn ọdọ agbegbe naa lo wa gbe oku wọn lọ ka awọn ọlọpaa mọle ni agọ ọlọpaa to wa nibẹ.

Àkọlé fídíò, Abisola Odebode: Ẹ wo àkàndá ẹ̀dá tó ń kọ́ àwọn àgùnbánirọ̀ l‘Osun ní ọ̀dà ṣíṣe lọ́fẹ̀ẹ́

Ọga ọlọpaa Ọdunlami ṣalaye siwaju pe ọga ọlọpaa ẹkun naa, Area commander lo yọju siwọn lọjọ naa to si pẹtu si wọn lọkan ki wọn to gbe oku naa kuro.

Bakan naa lo ni kọmiṣọna ọlọpaa nipinlẹ Ondo pẹlu ti ṣe abẹwo sibẹ to si ti fi da awọn olufgbe ibẹ loju iwadii yoo waye lati lee fi ọkan wọn balẹ pe ọlọpaa ko ni ohunkohun ni ipamọ lori iṣẹlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Banji Akitoye: Yoruba Nation nìkan ni 'Only Solution' lásìkò yíì, A kò kórira ẹ̀yà tó kù

Wàhálà ṣẹlẹ̀ nípìnlẹ́ Ondo nítorí ẹ̀sùn pe ọlọ́pàá ṣòkùnfà ikú èèyàn méjì àti Báàlẹ̀ ìlú

Ọrọ di bo o lọ, yago fun mi, nilu Kajola, ni ijọba ibilẹ Odigbo, nipinlẹ Ondo lọjọ Aiku, lasiko ti awọn ọdọ yabo agọ ọlọpaa to wa nibẹ.

Iroyin sọ pe awọn ọdọ naa gbiyanju lati dana sun agọ ọlọpaa ọhun, nitori ẹsun pe awọn ọlọpaa ibẹ pa eeyan mẹta, lara ẹni ti baalẹ ilu naa wa.

Àkọlé fídíò, Easter Celebration: Olórí Celestial ní Krìstíẹ́nì kò yẹ kó fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú àjíǹde

Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle sọ pe awọn ara ilu fi ẹsun kan pe nibi ti awọn ọlọpaa Kajola ti gbegi di ọna, lati da ọkọ duro ni opopona Eko si Benin, ni iṣẹlẹ naa ti waye ni irọlẹ ọjọ Satide.

Awọn eeyan mẹta ọhun to ti di oloogbe, David Olowofeyekun, Gbenga Abayomi, ati Kola Akinduro, to jẹ Baalẹ ilu Korede, n pada sile lati oko wọn, ni wọn kagbako iku ojiji.

Niṣe ni awọn ọdọ gbe oku awọn mẹtẹẹta siwaju olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Kajola, ti wọn si n kọrin pe awọn ko fẹ ọlọpaa ni agbegbe awọn mọ.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ sọ fun iwe iroyin 'The Guardian' pe "awọn ọlọpaa to gbegi di oju ọna, da awọn oloogbe duro, lori ọkada ti wọn wa, nibi ti wọn si ti n gbiyanju lati paaki ọkada wọn, ni ọkọ nla Hilux kan to n sare bọ kọlu wọn.

"Ọkọ Hilux naa n gbiyanju lati pẹ ọwọ si ẹgbẹ́, ki awọn ọlọpaa ma ba da a duro, lo lọ kọlu awọn oloogbe nibi ti ọlọpaa sọ pe ki wọn paaki ọkada wọn si."

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀

O ni pe : Lọgan ni wọn ku.

Eyi si lo mu ki awọn ara ilu to wa ni agbegbe ọhun ṣe iwọde, nibi ti wọn ti tọka si ọlọpaa kan pe oun ni balogun ikọ to ma n da awọn ọkọ duro lati gba owo lọwọ wọn loju popo.

Wọn ni awọn n fẹ ki wọn o gbe ọlọpaa naa kuro l'agbegbe awọn, lẹyin to ti lo bi ọdun mẹtadinlogun.

Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa, ati awọn oṣiṣẹ ajọ Amotekun, lo pana wahala ti ko ba ṣẹlẹ lọjọ Aiku.

Àkọlé fídíò, Oluyemisi Orisabiyi: Ẹ̀ẹ̀mẹta péré làwọn òṣìṣẹ́ KAI bẹ̀ mí wò, mo kọ̀wé sí wọn lái rí èsì

Kini awon agbofinro tun so?

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, arabinrin Funmilayo Odunlami, sọ fun awọn akọroyin pe awọn oloogbe naa gbé ọkada wọn gba oju ọna ti ko yẹ, ni wọn fi kagbako ijamba ọkọ.

"Niṣe ni wọn gba 'one way', ti ọkọ to n bọ lati ibi ti wọn kọju si, fi kọlu wọn. Kii ṣe awọn ọlọpaa wa lo fa iku wọn rara."

Àkọlé fídíò, Female Carpenter: Fatia Garu ní ọ̀pọ̀ èèyàn ni kìí gbàgbọ́ pé obìnrin ló ń ṣiṣẹ́ Káfíńtà

Kii ṣe igba akọkọ re e ti awọn araalu n fi ẹsun kan awọn ọlọpaa pe, wọn sẹ okunfa iku awọn ero ọna, nitori bi wọn ṣe ma n da ọkọ duro lati gba owo lọwọ wọn.

Lara iru awọn iṣẹlẹ bayii, lo fa iwọde ENDSARS to mi gbogbo orilẹ-ede Naijiria tìtì fun ọsẹ meji, lọdun 2020.

Awọn ọdọ fẹhonu han tako ifiyajẹni lọwọ ọlọpaa, lilọ ni lọwọ gba, ati awọn ẹsun miran.