Ondo civil servant suspended: Òṣìṣẹ́ ìjọba gba àṣẹ lọ rọọ́kún nílé nítorí ìròyìn òfégè ìkú nípa Gómìnà Akeredolu

Rotimi Akeredolu Aketi

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu Aketi

Ijọba ipinlẹ Ondo ti jawe lọ rọọkun nile fun oṣiṣẹ ijọba kan lori ẹsun pe oun gan lo wa nidi gbọyisọyi iroyin kan to kaakiri pe gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu ti jade laye.

Olori awọn oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni John Adeyemo ṣalaye nilu Akurẹ pe wọn ti fi orukọ oṣiṣẹ naa sọwọ si ajọ oṣiṣẹ ọba nipinlẹ naa fun ijiya to tọ.

O ni oṣiṣẹ naa, ẹni ti fi orukọ bo laṣiri gbe iroyin naa gadagba soju opo Facebook rẹ pe Akeredolu ti ṣalaisi.

Adari awọn oṣiṣẹ ọba nipinle Ondo naa wa fi kun un pe, irufẹ iwa bayii tako ilana omoluabi ati tiṣẹ ijọba n'ipinlẹ naa

Bakanna lo woye pe ijiya to tọ ni wọn yoo fi jẹ oṣiṣẹ ijọba naa lati duro bii ẹkọ nka fawọn agbọyisọyi oniroyin ofege laarin awọn oṣiṣẹ ijọba; eleyi to ni o n da ọpọlọpọ wahala silẹ lawujọ.

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

Ni ọjọ kini oṣu kẹrin ni gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu bẹrẹ isinmi ọlọdọọdun rẹ to si fa iṣakoso eto iṣejọba le igbakeji rẹ, Ọgbẹni Ayedatiwa lọwọ ni ibamu pẹlu ilana ofin orilẹede Naijiria.

Lasio to fi wa lẹnu isinmi yii ni iroyin ofege kan jade pe o ti jade laye lorilẹede Germany.

Ninu ọrọ to sọ ni ipadabọ rẹ, Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ni iwa ika patapata gba a ni iroyin naa ati pe o lọwọ kan oṣelu ninu

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Gbẹ̀fẹ́ ní àkókò tí mo lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àìrì aya mi nìkan ní ìyàtọ̀