Convicted Ex-govenor State Pardon: Mẹ̀kúnù ní láti dìde jà fún ara wọn - Falana

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gbajúgbajà òǹkọ̀wé, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka ti bu ẹnu àtẹ́ lu Ààrẹ Muhammadu Buhari fún bíbojú àánú wo àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Plateau, Joshua Dariye àti ti ìpínlẹ̀ Taraba Jolly Nyame.
Àwọn gómìnà méjèèjì ló ń sẹ̀wọ̀n lọ́wọ́ fẹ̀sùn jíjí owó ìlú lásìkò tí wọ́n ń ṣe ìjọba gẹ́gẹ́ bí gómìnà Ìpínlẹ̀ wọn.
Ní Ọjọ́bọ̀, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Kẹrin ni ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ orílẹ̀èdè yìí bójú àánú wo àwọn gómìnà náà pé kí wọ́n máa lọ sí ilé wọn láyọ̀ àti àlàáfíà lẹ́yìn tí wọ́n lo ọdún mẹ́rin mẹ́rin nínú ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá àti ọdún méjìlá tí wọ́n fún wọn.
Soyinka ní ìgbésẹ̀ Ààrẹ yìí dàbí ìgbà tí Ààrẹ bá mọ̀-ọ́n-mọ̀ fọ́ ẹyin òbí sí ojú àwọn ènìyàn, wọn kò ní gbàgbé rẹ̀ fún ìgbà pípẹ́.
Nínú àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Soyinka ní òun faramọ́ ẹni ọ̀wọ̀ Matthew Kukah, lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ tako Ààrẹ Buhari.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu wí pé ìjọba tó ń fi ojoojúmọ́ pariwo wí pé ìwà àjẹbánu ló sọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sínú oko ìdààmú tó wà báyìí ni yóò fún àwọn tí wọ́n dá lẹ́bi ṣíṣe owó ìlú kúmọkùmọ ní ìdáríjì, tí wọn yóò bọ́ okùn ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn wọn.
Ó fi kun wí pé nínú èrò tòun, kò sí ìrètí fún àwọn ọmọ Nàìjíríà mọ́ nítorí ọsàn tó yẹ kó so dídùn náà ló ti ń fúnni ní kíkan mú.
Bákan náà, nínú èrò tirẹ̀, gbajúgbajà ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn tó tún jẹ́ àgbà ọ̀jẹ̀ agbẹjọ́rò, Femi Falana ti rọ àwọn ará ìlú pàápàá àwọn tó forí sọgbà ìwà àjẹbánu àwọn gómìnà méjèèjì náà láti wọ́ ìjọba àpapọ̀ lọ sí ilé ẹjọ́ nítorí bí wọ́n ṣe dá àwọn gómìnà náà sílẹ̀.
Falana ní ohun tó yẹ àwọn ènìyàn ìpínlẹ̀ Taraba àti Plateau, tó yẹ kí àwọn gómìnà ọ̀hún lọ àwọn owó tí wọ́n kó jẹ náà láti fi ṣe àkànṣe iṣẹ́ fún pé ìjọba lẹ́jọ́ ni láti bí ijoba ìdí tó fi gbé ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Nínú àpilẹ̀kọ kan tó gbé kalẹ̀ níbi ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan ni Falana ti ní àsìkò ti tó báyìí fún àwọn mẹ̀kúnù ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà fi ohùn ṣọ̀kan láti jà fún ẹ̀tọ́ wọn.
Nígbà tó ń fi èrò rẹ̀ hàn lórí ìpinnu ìgbìmọ̀ àwọn olórí orílẹ̀ èdè yìí láti bojú àánú wo àwọn gómìnà tó ń sẹ̀wọ̀n lórí ìwà àjẹbánu, Falana ní ìwà jẹ́ yíyí òfin padà láti ṣègbè lẹ́yìn àwọn kan.
Bákan náà ló ní èyí túmọ̀ sí wí pé àwọn kan wà ní orílẹ̀ èdè yìí tó jẹ́ atóbi má ṣebáwí tí àparò wọn gorí ebè.
Ó ní èyí ti fojú hàn wí pé ìyàtọ̀ gedegbe wà láàárín àwọn olówó àti mẹ̀kúnù ní Nàìjíríà.
Bẹ́ẹ̀ náà ló wá pàrọwà sí àwọn mẹ̀kúnù láti ṣe ara wọn lọ́kan gẹ́gẹ́ bí àwọn olówó ṣe ń ṣe láti lè jà fún ẹ̀tọ́ wọn nípa bíbéèrè fún ìgbé ayé tó rọrùn.

















