Ukraine Returnee: Oreoluwa Opalana sọ bí Ọlọ́run ṣe kóo yọ tí ó sá kúrò ní Ukraine padà wá Nàìjíríà

Àkọlé fídíò, 'Fásitì Nàìjíríà kò gbà mi wọlé ló mú mi sá lọ Ukraine, àmọ́ ohun tí ojú mi rí nínú ogun náà rèé kí ń tó sá wá Nàìjíríà'

Bi mo ṣe ń rii lori iroyin awọn amohumaworan, gbogbo ibi ti mo maa n rin si ni Ukraine to fi mọ ile ẹkọ mi, gbogbo ẹ ni wọn ti jo nina danu".

Ọrọ ree lẹnu ọmọ orilẹede Naijiria to fi Russia ṣe ibugbe nibi ti wọn ti n ṣina ogun bo orilẹede Ukraine.

O ni "kii ṣe nkan kekere ni ki eeyan maa gbọ ninu iroyin nipa ibi ti awọn eeyan ti mo maa n ba rẹrin, ki n si ma mọ alafia wọn".

Opalana Oreoluwa ba BBC Yoruba sọ ẹkunrẹ́rẹ iriri rẹ ati awọn mii lati igba ti ogun Russia ati Ukraine ti bẹrẹ.

O wa lara awọn ọmọ Naijiria to n ka iwe ni Ukraine amọ ti wọn sa wale.

O ni tori Fasiti Naijiria ti oun kọkọ fẹ lọ lẹyin girama kọ gba fun oun lati kọ imọ ẹkọ to wu oun lo mu ki oun sa lọ ṣe imọ ẹkọ iṣegun oyinbo ni Russia.

"Ki ija yẹn to ṣẹlẹ ni ẹru ti n ba awọn mọlẹbi mi".

Oreoluwa ṣalaye bi wọn o ṣe gbudọ kuro ni ileewe bo ba ṣe wu wọn tori akẹkọ imọ iṣegun oyinbo ni.

Paapaa lasiko to ni awọn olukọ awọn n ki awọn laya pe ko si nkankan ti yoo ṣẹlẹ afigba to eyi ti wọn o le da ṣe mọ ti wọn n gbọ iro ado oloro kaakiri.