Russia-Ukraine war: Tọkọtaya darapọ̀ mọ́ iléèṣẹ́ ológun láti dáàbò bo Ukraine

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọpọlọpọ ọmọ orilẹ-ede Russia lo wa, to jẹ pe inu iwe itan ati eyi ti awọn baba nla wọn sọ fun wọn nikan ni wọn ti gbọ nipa ogun ri.
Ṣugbọn ni bayii, awọn naa ti darapọ mọ awọn ọmọ ogun lati koju Russia.
Ni ibudo kan ti wọn ti n kọ iṣẹ ogun jija ni ilu Odessa, a ri ololufẹ meji kan to jọ n kọ ogun jija.
Oriṣiriṣi awọn akọṣẹmọṣẹ ati oṣiṣẹ lo n kọ nipa lilo nkan ijagun, ati bi a ṣe n tọju ẹni to ba gba ọgbẹ loju ogun.
Awọn kan lara wọn ti ẹ tun n ṣe e pẹlu ololufẹ wọn, lati daabo bo orilẹ-ede wọn lọwọ ogun.
Lara wọn ni Olga Moroz ati Maxim Yavtushenko.
Oṣu diẹ si asiko yii lo yẹ ki arabinrin Olga Moroz, ati afẹsọna rẹ, Maxim Yavtushenko, ṣe igbeyawo wọn.
Olga, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn sọ pe gbogbo eeyan lo yẹ ko mọ bi a ṣe n jà, bi a ṣe le po oogun pọ, lati le fi tju ẹbi ati awọn eeyan miran to ba nilo itọju.
Ni ero tiẹ, Yavyushenko sọ pe bi awọn ṣe n kọ ogun jija ti mu ki oun gbaradi fun nkan yoowu ti yoo ba ṣẹlẹ si oun ninu ogun naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Awọn ati awọn eeyan miran n gbaradi de asiko ti awọn ọmọ ogun Russia yoo sunmọ ilu wọn.
Ni ibudo naa, eeyan bi ọgọrin si aadọjọ ni wọn n kọ ni awọn imọ pẹẹpẹẹpẹ nipa iṣẹ ologun, ni ibudo naa lojumọ.
- Wo ìdí pàtàkì mẹ́ta tí Russia se kọlu Ukraine
- Wo àwọn àṣìṣe ikọ̀ ológun Russia ní Ukraine
- Ológun ní kí aya mi bọ́ aṣọ kúrò lára, pa ọmọ mi mẹ́rin àtàwọn alátìlẹyìn mi - El Zakzaky
- Sé lóòtọ́ọ́ ní ọlọ́pàá yìnbọn mọ́ àgùnbánirọ̀ n'Ibadan?
- Nàíjíríà ń sún ọjọ́ ìjà síwájú ni, mo gbà pé ìpàdé àpérò gbọdọ̀ wà - Ọba Tejuosho
Ilu Odessa yii ni papakọ omi Black Sea wa, nibi ti ẹru n gba wọle tabi jade julọ ni Ukraine, wa. O si jẹ ara awọn ibi pataki ti Russia fẹ ẹ kọlu.
Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Keji, ni Russia bẹrẹ ikọlu si Ukraine.
O si ti kapa awọn ilu nla bi Mariupol.
Ilu to gbajumọ, alafẹ ati awọn ileeṣẹ nla ni Odessa.
Ko ti i si ẹni to mọ asiko ti ogun naa yoo pari, ṣugbọn iroyin sọ pe aarẹ Ukraine, Volodymyr Zelensky, ti pe akẹẹgbẹ rẹ ni Russia, Vladimri Putin pe ko jẹ ki awọn ṣe ipade ijiroro lori ogun naa.
Lasiko kan to n ba awọn orilẹ-ede naa sọrọ ninu fidio kan lo ṣe ipe naa.
















