Russia and Ukraine crisis: Russia ń kọlu àwọn iléèwé àti iléèwòsàn ní Ukraine, igbákejì olóòtú ìjọba Ukraine sọ̀rọ̀ síta

Orilẹede Russia n rọjo agba oloro sawọn agbegbe tawọn araalu pọ si, ninu eyi ti awọn ileewosan, jẹleosinmi atawọn ileewe ni Ukraine.
Igbakeji olotu ijọba orilẹede Ukraine, Olha Stefanishya ṣalaye fun BBC pe lẹyin iduroṣinṣin awọn ologun Ukraine, nṣe lawọn ologun Russia n doju ija kọ awọn araalu.
- Ó yá, àsìkò tó kí o tan iná wádìí gbogbo owó tí wọ́n ti ná lórí ibùdó ìfọpo ní Nàìjíríà - SERAP kọ̀wé sí Buhari
- Bí àwọn ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ lọ ran Ukraine lọ́wọ́ lójú ogun ṣe tàdí mẹ́yìn rèé nígbá tí wọ́n gbọ́ "wàa san $1,000"
- Njẹ́ o dá ayédèrú ìròyìn mọ̀ tí o bá ri i?
- Mọ̀ síi nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó dèrò àtìmọ́lé nítorí ìwọ́de lòdì sí Russia
Ẹwẹ ajọ ilera agbaye, WHO pẹlu ni Russia n kọlu awọn ibudo ilera kaakiri Ukraine.
Oludari agba ajọ WHO, Tedros Adhanom Ghebreyesus ṣalaye lọjọ Aiku pe, "Ajọ WHO ti fidi rẹ mulẹ pe ọpọ ikọlu lo waye lawọn ibudo ilera kaakiri Ukraine eyi si n fa ọpọlọpọ iku ati ọgbẹ,"
Bakan naa ni ijọba ilẹ Gẹẹsi ti n fẹsun kan Russia pe o n doju ija kọ awọn agbegbe ti ọpọ ero wa.
Ilẹ Gẹẹsi ṣalaye pe iru ọgbọn ti "Russia lo niyi ni Chechnya lọdun 1999 ati Syria ldun 2016, nipa lilo ohun ija ofurufu ati oriilẹ lọwọ kan naa,"

Lọjọ Satide, awọn alamojuto fun ajọ iṣọkan agbaye, UN sọ pe ọtalelọọdunrun o din mẹsan eeyan ni wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti ku latigba ti Russia ti ṣigun wọ Ukraine ljọ kẹrinlelogun oṣu keji amọṣa ko si aniani pe iye awọn to ti ku yoo ti ju eyi lọ daadaa.
Ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri labẹ ajọ iṣọkan agbaye, UNHCR ni o le ni miliọnu kan abọ eeyan to ti di atipo ti wọn si ti fi orilẹede Ukraine silẹ nitori ikọlu Russia.
Amọṣa, Russia ti daa pada pe awọn ko kọju ija si araalu rara, o ni eto ologun lati koju awọn to n ja fun ominira Ukrain atawọn to n tẹle ila Nazi lorilẹede Ukraine loun gunle.
Nibayii naa, ko din ni ẹẹdẹgbẹsan eeyan ti wọn ti fi si ahamọ kaakiri awọn ilu mẹrinlelogoji lorilẹede Russia fun kikopa ni iwọde tako ohun ti Russia n ṣe ni Ukraine, gẹgẹ bi ajọ ọlọfintoto OVD-Info ṣe sọ.
Russia kéde ìdádúró ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ìlú méjì ní Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bí ìkọlù tí orílẹ̀ èdè Russia ń ṣe sí orílẹ̀ èdè Ukraine ṣe wọ ọjọ́ kẹwàá lónìí, Russia ti kéde pé òhun kò ní ṣe ìkọlù sí àwọn ìlú méji kan ní orílẹ̀ èdè Ukraine fún ìgbà díẹ̀ ná.
Àwọn ohun tó wà nínú ìkéde tuntun yìí nìwọ̀nyí:
- Ilé iṣẹ́ ètò ààbò Russia ti kéde pé àwọn yóò dáwọ́ dúró, tí àwọn yóò sì gba àwọn ará ìlú láàyè láti kúrò nílùú láti aago mẹ́wàá aago ilẹ̀ Russia tó ń ṣe aago méje òwúrọ̀ ti wa níbí lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ní àwọn ìlú Mariupol àti Volnovakha.
- Russia kéde ìdádúró ṣíṣe ìkọlù sí àwọn ìlú méjì ní Ukraine
- Russia ti gbà láti ṣi ọ̀nà fún àwọn tó fẹ́ kúrò nílùú ṣùgbọ́n Ukraine kò ì tíì fi ìdí èyí múlẹ̀.
- Mauripol ló ti wà lábẹ́ àkóso àwọn ọmọ ogun Russia, bákan náà ni ìkọlù tó lágbára ti wáyé ní Volnovakha.
- Ṣaájú ni Méyọ̀ ìlú Mauripol ti bẹ̀bẹ̀ pé kí àwọn ará ìlú kúrò ní ìlú náà pẹ̀lú bí àwọn ọmọ ogun Russia ṣe ti díwọ́n mọ́lé.
- Yàtọ̀ sí àwọn ìlú méjì wọ̀nyìí, ogun ṣì ń tẹ̀síwájú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àdó olóró ló ti dún gbàmù ní Kharkiv, tó wà ní ìlà oòrùn Ukraine.
- Ní ìlú Sumy, àwọn ọmọ Russia ti bẹ̀rẹ̀ sí ní dí wọn mọ́lé láti aago márùn-ún ìdájí gẹ́gẹ́ iléeṣẹ́ ìròyìn Ukraine ṣe sọ.
Awon iroyin mii ti e le ni ife si:
- Ọlọ́pàá tó gbé oúnjẹ tẹ̀lé ènìyàn nínú fọ́nrán tó gba ìgboro yóò fojú winá òfin
- Ohun ìṣeré abánilòpọ̀ há sójú ara mi, mo kú tán - Obìnrin ológun kan
- Wo àwòrán bí Ukraine ṣe rí tẹ́lẹ̀ ṣáájú ìkọlù Russia àti bó ṣe rí báyìí
- Ìdí rèé tí mo ṣe fẹ́ jẹ ààrẹ Nàíjíríà - Tinubu
- Ẹ sọ́ra fún wíwá owó òjijì ẹ̀yin ọ̀dọ́, ìgbẹ̀yìn rẹ kìí dára- Alake Egba
- Ibá Lassa fojú hàn ní ìpínlẹ̀ Oyo, ó ti mú ẹ̀mí Dókítà méjì lọ
- Sé Nàìjíríà le fi Abba Kyari ráńṣẹ́ sí Amẹ́ríkà pẹ̀lú bó ṣe ń kojú ìgbẹ́jọ́ àjọ NDLEA? – Àlàyé rèé


















