Ukraine Russia war: Àwọn àfojúsùn ọ̀nà àbáyọ márùn ùn tí ogun yìí lè padà kángun sí

Aworan awọn ọmọ ogun Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, James Landale
    • Role, Diplomatic correspondent

Bi ogun to n mu gbogbo nkan ṣokunkun lorile-ede Ukraine yi ṣe n tẹsiwaju si, a ti ri ọna abayọ seese ko fẹ le diẹ ṣugbọn kii ṣe pe ko si rara.

Iroyin to n tẹwa lọwọ lati oju ogun, ati aisi ọrọ ijiroro ati bi awọn eeyan ṣe n ṣe idaro, gbogbo rẹ le pin eeyan lẹmi lootọ.

Amọ Yoruba bọ, wọn ni bí a ba n sunkun, a maa ri ran.

Ki ni awọn nkan tawọn to wa lori ipo le ṣe ti yoo mu ki ogun yi wa si opin?

Ati awọn ologun naa, ki gan an lawọn ọna abayọ to wa nilẹ fun wọn?

Diẹ ree ninu awọn nkan takroyin wa woye pe o ṣeeṣe ki o mu opin ba ikọlu Russia si Ukraine yi.

line

Ki ogun yi yara pari:

Ki eleyi to le ṣẹlẹ, awọn ọmọ ogun Russia yoo ni lati jara maa ikọlu wn si Ukraine.

Awọn ikọlu ranpẹ ti wọn n ṣe lasiko yi , alekun yoo ba ti wọn yoo si kogun ja Ukraine taara.

Gbogbo nkan amu sagbara Ukraine ni wọn yoo bajẹ ti olu ilu Ukraine iyẹn Kiev yo si bọ si ọwọ Russia.

Bi eleyi ba ti ṣẹlẹ tan, ohun to ku ni ka gbọ pe wọn pa aarẹ Zelensky tabi ko si ṣe pe o sa nilu.

Kini o le sele leyin odi?

Lẹyin odi, o le da ijọba tiẹ silẹ ṣugbọn Russia ni yoo maa se akoso pẹlu ẹni ti wọn yan sipo.

Ọkẹ aimọye ni yoo ku ti ọpọ ko si ni nile lori.

Russia yoo kede pe awọn jawe olubori ti Ukraine yoo si darapọ mọ Belarus gẹgẹ bi orileede to wa labẹ akoso Russia.

Àkọlé fídíò, Aáwọ̀ tó ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine ti mú àlékún bá iye owó epo rọ̀bì lágbàyé

A ko le sọ pe iru nkan bayi ko ni waye ṣugbọn yoo ni awọn nkan to gbọdọ ṣẹlẹ.

Ninu rẹ ni pe ki awọn ọmọ ogun Russia ja ju bi wọn ṣe n ja yi lọ, ki irẹwẹsi ọkan si ba awọn ọmọ ogun Ukriane.

Bi eleyi ba file waye, ogun naa ko ni pẹ pupọ amọ bi ẹni fi ina sori orule sun ni.

Awọn ti wọn gba orileede mọ lọwọ ko ni sinmi titi ti wọn yoo fi gba ilẹ wọn pada.

O ṣeeṣe ki ogun yi gberi lẹyin to ba dopin ni kiakia bayi.

Àkọlé fídíò, Láti sẹ́ńtúrì kẹrìnlá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín Russia àti Ukraine

2. Ogun ọlọjọ pipẹ le waye

Oseese ko jọ pe ogun yi le tẹsiwaju fọjọ pipẹ bi wọn ṣe n baa lọ yi.

Boya awọn ọmọ ogun Russia yoo sinmi diẹ yala nitori pe wọn ko ni nkan ogun mọ tabi ki awọn adari maa se ṣegeṣege

O ṣeeṣe ki ogun yi pẹ si ki wọn ma tete ribi gba akoso Kiev.Russia le rọ yika Ukraine ṣugbọn wn le ma ribi wọle.

Awọn ọmọ ogun Checnya lasiko ikọlu Grozny

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Boya ti Russia ba si ti gba akoso lawọn ilu Ukraine kọọkan, awọn araalu ṣi le ma ba wọn ja ogun abẹle.

Boya mii tun ni pe Russia le ma ni ọmọ ogun to to lati koju orileede to tobi bi Ukraine yi.

Bakan naa lawọn alabaṣepọ Ukraine le fun wọn ni nkan ija lati le fi mu ki ogun naa pẹ ju bo ṣe wa yi lọ.

Koda, o tun ṣe ṣee ko jẹ pe lẹyin ọpọ ọdun ti wọn fi n ja ogun yi, Russia le ko ẹru wọn kuro bi Amẹrika ti ṣe ṣe ni Afghanistan lẹyin ọpọ ọdun ikogunja ilẹ naa.

line

3, Ogun le ran de ilẹ Yuroopu lapapọ:

Njẹ o ṣeeṣe ki ohun yi ran kọja ibode orileede Ukraine bi?

Aarẹ Putin le fẹ gba ilẹ forileede Russia nipa riran awọn ọmọ ogun l si Ukraine lati Moldova ati Georgia to ṣe pe wọn ko si lara Nato.

Tabi ki nkan si ma lọ bo ṣe rọ ki wahala miran tun bẹ silẹ.

Koda, o tun le sọ pe bi awọn ilẹ Yuroopu mii ṣe n fi nkan ija ranṣẹ si Ukraine jẹ idoju ija kọ ilẹ rẹ ko si loun yoo gbẹsan.

O le leri lati fi awọn ọmọ ogun ranṣẹ si awọn ilẹ ti kii se ọmọ ẹgbẹ Nato bi Lithuania eyi ti yoofun lanfaani lati nasẹ de Kaliningrad.

Aworan ababọ ikọlu Russia si ilu Kharkiv

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eleyi le mu ki ogun waye laarin Russia ti awọn orileede Nato.

Idi ni pe labẹ ofin Nato bi eeyan ba doju ija kọ orileede kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ wọn bi igba pe o doju ija kọ gbogbo awọn to ku ni.

Bi eyi ba waye, Putin le ma bikita ko si tẹsiwaju lọna ti fẹsẹ ijọba rẹ rinlẹ.

Àkọlé fídíò, Èdè Yorùbá dùn ún gbọ́ àti láti sọ, mo sì fẹ́ràn kí n máa sọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà

4. Wọn le yanju ọrọ naa ni itubi n nubi

Njẹ ijiroro ati ọrọ pẹlẹ le waye mọ pẹlu gbogbo ohun to n ṣẹlẹ yi?

"Ibọn n dun gbamu gbamu bayi ṣugbọn a ko gbọdọ pa ilẹkun ijiroro de''

Ọrọ ree ti ọga agba ajọ UN António Guterres sọ lori ikọlu yi.

Dajudaju ijiroro gbọdọ maa waye si.

Aarẹ Macron ti ba aarẹ Putin sọrọ lori foonu.

Awọn aṣoju ilẹ ni awọn n ẹti leko lati mọ bi nkan ṣe n lọ ni Moscow.

Lẹyi to si jẹ iyalẹnu, awọn aṣoju Russia ati Ukraine ti ṣepade pọ ni Belarus

Nkjan ko ti ni iyanju ṣugbọn pe aarẹ Putin tiẹ gba pe ki wọn pade sọrọ, nkan le tun niyanju ju bẹ lọ.

Ohun tawọn aṣoju ilẹ mejeeji n sọ ni pe o ṣe pataki ki aarẹ Russia mọ nkan tawọn ilẹ Wẹsti lawọn fẹ ki wọn to le gbe ijiya kuro lori ilẹ rẹ.

line

5. Bi wọn ba yẹ aga nidi Putin nkọ?

Ero yi dabi ala nitori ko daju pe yoo waye ki wọn yẹ aga nidi Putin.

Amọ igba kan ko lọ bi oreere tori naa ki a maa fọkan si pe ko le ṣẹlẹ rara ati rara.

Laarin ọsẹ taa wa yi ni ọjọgbọn Lawrence Freedman ti fasiti Kings College ni London kọ ọrọ pe''Bayi o ṣeeṣe ki wọn gba ijọba ni Moscow bo ti ṣe waye ni Kiev''

Awọn ọlọpaa mu oluwọde lasiko ifẹhonuhan tako ikọlu ti Russia ṣe si Ukraine

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki lo mu sọ ọrọ yi? Abi lootọ ni pe Putin n ja ogun ti ko bojumu lootọ́?

Ọkẹ aimọye ọmọ ogun le tara rẹ ku, ki ijiya ọrọ aje bẹrẹ si ni lapa.

Putin le ma ri atilẹyin lati ọdọ araalu bi ti tẹlẹ, koda awọn to n gbero yiyẹ aga nidi rẹ le bẹrẹ si ni gbori.

Putin le loun yoo mu awọn ogun lati fi tẹ wọn mọlẹ. Wahala le di ranto ki iditẹgbajọba waye.

Aba ni nkan taa n da yi ati pe awọn to ti n jẹ anfaani ijọba Putin naa le ma gba ki iru nkan bayi waye.

Wọn ko ni fẹ ki eeyan kankan da iyepẹ sinu gari wọn.

Aba tabi afojusun yi le waye ṣugbọn ko si aridaju pe o le ṣẹlẹ bẹẹ

Lakotan

Awọn nkan taa foju sun pe o le ṣẹlẹ latari ogun to n ja lọwọ yi yi le ma da nikan ṣẹlẹ.

O ṣeeṣe ki meji tabi mẹta waye ninu wọn yala lẹẹkan naa tabi ni ṣiṣẹ n tẹle.

Amọ, ko si bi nkan ṣele waye ti ko ni lapa lori bi nkan ti seri tẹlẹ lagbaye.

Oju apa lọrọ to wa nilẹ yi, ko le jọ oju ara mọ lopin igba ti Russia ti bẹrẹ ogun pẹlu Ukraine yi.