Russia-Ukraine War: Wo àwọn àwòrán tó ń sọ nípa ogun tó ń lọ lọ́wa láàrin orílẹ̀èdè méjéèjì

Ọpọ ọkọ loju popo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ilu wo lo fẹ gbalejo ọpọ eeyan to n sa kuro nilẹ Ukraine bayii nitori ogun Russia?

Nibayi ti orilẹede Russia ti gbe ikọlu ka orilẹede Ukraine mọle, ọpọ ẹmi ti sun, dokia ti bajẹ, tawọn eeyan si n sa asala fun ẹmi wọn.

Koda, awọn asaaju orilẹede lagbaye ni wọn ti n ke si ara wọn lati dide loju oorun wọn lori ikọlu Russia si Ukraine.

Akoko yii si lo buru diẹ ni ilẹ Yuroopu bayii lẹyin ogun abẹle keji, gẹgẹ bi ọga agba fọrọ ilẹ okeere labẹ ajọ isọkan ilẹ Yuroopu, Josep Borrell se sọ.

Gẹgẹ bo se wi, ajọ EU yoo fofin to lagbara de orilẹede Russia, iru eyi ti ko tii sẹlẹ ri.

Nibayii, ẹ wa wo awọn aworan to sọ nipa bi ogun naa se n lọ ati awn ohun to ti fori sọta isẹlẹ naa.

Ọkunrin to n ronu ati ọkọ to bajẹ
Àkọlé àwòrán, Ibanuje dori agba kodo! Ado oloro ba mọto ọkunrin yii jẹ, ironu de fun
Awọn ile ti ado oloro ba nilẹ Ukraine
Àkọlé àwòrán, Awọn ile ti ado oloro ba nilẹ Ukraine
Ero to wa ni ibudo reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Obitibiti ero lo peju si papa isere reluwe nilu Kylv nibayi ti ariwo ikọlu lori afẹfẹ gbode kaakiri ilu naa.

Ọpọ eeyan lo gbe baagi ati apoti ẹru lọwọ, ta si mọ boya wọn n sa kuro ni orilẹede naa ni.

Awọn to sa si ibudokọ reluwe
Àkọlé àwòrán, Baba kan n pẹtu sawọn ọmọ rẹ ninu nibi ti mọlẹbi wọn fi ara pamọ si ni ibudo reluwe
Obinrin to fi agbelebu sori nigba to gbọ nipa ado oloro to bu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Obinrin kan n gbadura ni gbagede ominira to wa nilu Kyiv, tii se olu ilu Ukraine
Awọn to sa si ibudokọ reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn mọbinrin yii lo sa pamọ sibudokọ reluwe, ti wọn si n tẹ foonu wọn lati mọ ohun to n lọ nigboro
Awọn to sa si ibudokọ reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan to n di mọ ara wọn , wọn ko fẹ ki ogun ya wọn
Ọpọ ọkọ loju popo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ọpọ eeyan gbe mọto wọn lati sa kuro nilu Kyiv, tii se olu ilu Ukraine lati sa lọ tori ikọlu ogun Russia
Awọn ologun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Kaakiri ilẹ Ukraine ni awọn ologun Russia wa lati sẹru ba awọn eeyan ilẹ naa
Awọn ile ti ado oloro ba nilẹ Ukraine
Àkọlé àwòrán, Awọn ile ti ado oloro ba nilẹ Ukraine
Awọn to sa si ibudokọ reluwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn mọlẹbi kan ree to joko sinu ibudo reluwe lai mọ ireti fun ọjọ ọla wọn