Russia-Ukraine Crisis: Olóòtú ìjọba UK bá ilé aṣòfin sọ̀rọ̀ lórí aáwọ̀ tó ń wáyé

Boris Johnson

Oríṣun àwòrán, Reuters

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Boris Johnson ti kede pe UK ti fofin de ile ifowopamọ orilẹ ede Russia márùn un lẹyin ti Russia ni k'awọn ọmogun rẹ wọ apa ila oorun Ukraine.

Bakan naa UK tun fofin de ọlọrọ ilẹ Russia mẹta lori ọrọ Ukraine kan náà.

Ọgbẹni Johnson ni Russia ti yabo Ukraine lọna aitọ ati pe ọrọ naa le di aawọ ọlọjọ pipẹ.

O ni ilẹ UK yoo ṣe afikun ijiya yii ti Russia ko ba yi iwa pada.

Ajọ EU ilẹ Yuroopu ati oril'ede Amerika naa ti fofin de Russia.

Igbesẹ Aarẹ Vladimir Putin to jẹ kí UK fofin de Russia:

Lọjọ Aje ni Aarẹ Vladimir Putin paṣẹ pe ki awọn ọm'ogun Russia wọ ẹkun Donetsk ati Luhansk lẹyin to ri wọn gẹgẹ bi ẹkun olominira.

Aarẹ Putin ni ipẹtu sija l'awọn ọmogun lọ ṣe níbẹ.

Amo, ilẹ Amẹrika ni ọrọ runrun ni Putin n sọ.

Ẹwẹ, olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, Johnson fẹsun kan Aarẹ Putin pe o n fi ẹtọ Ukraine dun un gẹgẹ bi orile-ede olominira.

Boris Johnson ba ile aṣofin sọrọ lori ọrọ Russia:

Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi ṣalaye fun ile igbimọ aṣofin pe ijọba UK yoo fofin de banki Russia marun un ti orukọ wọn n jẹ: Rossiya, IS Bank, General Bank, Promsvyazbank ati banki Black Sea.

Ọgbẹni Johnson tun awọn ọlọrọ mẹta to jẹ ọmọ Russia ti UK tun fofin de ni Gennady Timchenko, Boris Rotenberg ati Igor Rotenberg.

Ijọba ti gbẹsẹ le dukia wọn ni UK, bakan naa ni wọn o le rinrin ajo wọ UK mọ bayii.

Johnson tun fi idunnu rẹ si igbesẹ Germany lati fagile iwe ẹri ọpa gaasi Nord Stream 2 to lọ sí Russia.

Bakan naa ni ajọ EU ti kede pe oun ti fofin de awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin Russia at'awọn banki to n nawo lori ileeṣẹ ọm'ogun Russia.

Ikede Johnson jade lẹyin ti Aarẹ Joe Biden Amerika ti kọkọ kéde pe oun ti fofin de gbogbo idokowo tuntun, at'awọn okowo Amerika to wa ẹkun Ukraine to fẹ ya kuro lara Ukraine.

Ki lo de ti UK fofin de kikida awọn olowo mẹta ati banki marun un yii?

Iroyin lati Russia fidi rẹ mulẹ pe awọn ọlọrọ mẹtẹẹta yii ni wọn jẹ alabaṣiṣẹpọ pẹlu aarẹ Putin.

Koda, ọrẹ ati kekere ni Rotenberg jẹ fun Putin.

Owo ati dukia Rotenberg jẹ $1.2bn nigba ti ọmọkunrin ẹgbọn rẹ, Igor ni owo ati dukia to to $1.1bn.

Timchenko sì jẹ ẹni to lowo julọ ṣikefa lorilẹ ede Russia.

Banki Promsvyazbank jẹ ile ifowopamọ orilẹ ede Russia eleyii ti UK ni o n sagbateru fawọn ọm'ogun Russia.

Banki aladani ni Rossiya ti o si tun lọwọ ninu ileeṣẹ tẹlẹfisan kan.

Black Sea jẹ banki apa Crimea eleyii ti wọn da silẹ lọdun 2014.

Olootu ijọba UK tun sọ pe ko yẹ ki Russia gbalejo ifẹsẹwọnsẹ aṣakagba idije UEFA Champions League.

Akọwe ijọba lori ọrọ aṣa, Nadine Dorries naa sọ pe Russia ko yẹ ni ẹni tí o yẹ ko gbalejo idije ere idaraya kankan.

Amin iyasọtọ kan

UK ní Russia ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine

Ọmọ ogun kan to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Reuters

Agbọ́n ń ṣẹ́, oyin ń ṣẹ́, ojú olóko sì rèé kọ̀ǹdùkọndu.

Orílẹ̀ èdè Britain ti ní àwọn yóò fi òfin de Russia nítorí tó ni bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine.

Akọ̀wé ètò ìlera ilẹ̀ UK, Sajid Javid ló sọ èyí lẹ́yìn ìpàdé ìgbìmọ̀ aláṣẹ tí wọ́n ṣe.

Javid, nígbà tó ń bá ikọ̀ ìròyìn Sky News sọ̀rọ̀ ní ó fojú hàn pé Russia ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù sí Ukraine pẹ̀lú bí Russia ṣe ti kó àwọn ọmọ ogun àti àwọn ohun èlò ìjà ráńṣẹ́ sí Ukraine.

Ó ní ohun tí Yúròòpù ń kojú lásìkò yìí kò da rárá pẹ̀lú pé ẹ̀rí ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ààrẹ Russia, Putin ti ṣetán láti kógun ja Ukraine.

Bákan náà ló fi kun pé UK kò faramọ́ ìkọlù yìí.

Olootu àgbà ilẹ̀ UK, Boris Johnson nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé pàjáwìrì COBRA ní Ààrẹ ilẹ̀ Russia, Vladimir Putin ti tẹ òfin àgbàyé lójú mọ́lẹ̀ nípa rírán àwọn ọmọ ogun sẹ́nu ibodè Ukraine pẹ̀lú èròńgbà láti da ìṣọ̀kan rẹ̀ rú.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Johnson ní lọ́gán ni àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ fífi òfin orílẹ̀ èdè àgbáyé de Ukraine.

Ó ní àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mú ẹ̀yẹ̀ bọ̀ lápò pẹ̀lú Russiani nítorí àwọn mọ̀ pé Russia ṣì máa ṣe àwọn hu àwọn ìwà kòtọ́ mìíràn.

Bákan náà ló ní Ààrẹ Putin ti ṣetán láti da ìṣọ̀kan àwọn orílẹ̀ èdè Yúròòpù rú, tó sì ní ìpadàbọ̀ rẹ̀ yóò burú ju bí àwọn ṣe lérò lọ.

Kí ló ti ṣẹlẹ̀?

Ààrẹ Russia, Vladimir Putin ní òun ti ṣàwárí ẹkùn méjì ní Ukraine tó jẹ́ pé Russia ló ń ṣe àkóso rẹ̀.

Putin ní òun yóò rán àwọn ọmọ ogun Russia lọ sí àwọn ìlí náà ìyẹn Luhansk àti Donetsk tí èyí sì ti ń dá ìbẹ̀rù-bojo kalẹ̀ wí pé ó le fa kí àwọn ọmọ yawọ àwọn ìlú náà.

Ó ní ìpẹ̀tù sááwọ̀ ni àwọn ọmọ ogun fẹ́ lọ sẹ ṣùgbọ́n àwọn aṣojú ilẹ̀ Amẹ́ríkà níbi ìpàdé àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé (UN) ní èyí kò tọ́ àti pé Russia fẹ́ yabo Ukraine ni.

Ìgbìmọ̀ ètò ààbò UN níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe ní New York lẹ́yìn ìkéde Putin pè fún àláfíà àti àgbọ́yé nítorí kí wọ́n le dènà ogun.

Aṣojú ilẹ̀ Russia ní orílẹ̀ èdè náà ṣetán láti yanjú ọ̀rọ̀ ọ̀hún ní tùbí ǹ nùbí ṣùgbọ́n tó fẹ̀sùn kan Ukraine pé ó mú ọ̀rọ̀ náà ju bótiyẹ lọ.

Bákan náà ló fi kun pé orílẹ̀ èdè Ukraine kò ní ìtàn àti pé Russia ló dá a sílẹ̀.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ọmọ abẹ́ Amẹ́ríkà ni Ukraine tí àwọn ọmọ ogun àpapọ̀ ilẹ̀ West sì ń dúnkokò mọ́ ètò ààbò Russia.

Ẹ̀wẹ̀, Ààrẹ Ukraine, Zelensky nígbà tó ń fèsì ní Ukraine kò bẹ̀rù ẹnikẹ́ni tí àwọn kò sì ní yí ìpinu àwọn padà.

Àkọlé fídíò, "Onírúrú ìdẹ̀yẹsí ni mò ń dojúkọ lẹ́nu iṣẹ́ nítorí mo jẹ́ obìnrin"

Kí ni Russia ń fẹ́ lọ́wọ́ Ukraine ?

Ní ọdún 2014 ni Russia gbẹ́sẹ̀ lé Crimea nígbà tí wọ́n ní àwọn ló ni ìlú náà.

Ukraine wà lára àwọn orílẹ̀ èdè Soviet Union tó túká lọ́dún 1991.

Russia fẹ̀sùn kan pé àwọn adarí Ukraine ń ṣe àwọn ètò tó lòdì sí Russia.

Bákan náà ni Russia ń bínú pé àdéhùn àláfíà Minsk tọ́dún 2015 lórí ìlà oòrùn Ukraine kò ì tíì jẹ́ mímú ṣẹ.

Russia ti jiyàn pé òun kò gbèrò láti kógun ja Ukraine ṣùgbọ́n kò dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ọmọ ogun tí Russia ti kó lọ sí ẹnu ibòdè Ukraine.