Money Ritual: Agbaṣẹ́ṣe akódọ̀tí ké gbàjarè lórí òkú àti ẹ̀yà ara èèyàn tí wọ́n ń rí nínú idọ́tí nígbà gbogbo

Ẹgbin to wa ni aarin ilu

Aye ti fẹlẹ, o ti fẹ lu jara wọn, koda o ti dori kodo pẹlu oriṣiiriṣii nkan to n ṣẹlẹ lọwọ yii.

Ọga agba ileeṣẹ kan to n ri si kiko idọti nipinlẹ Bayelsa, Bright Ayebakari ti sọ lori eto kan pe ọsọọsẹ l'awọn maa n oku awọn ọmọde, ẹyà ara eeyan to fi mọ ohun ija oloro ninu idọti nipinlẹ naa.

Ayebakari sọ fawọn akọroyin pe ko si lara iṣẹ awọn lati maa gbé òkú, ṣugbọn n ṣe l'awọn maa n ri oku ni gbogbo igba ninu idọti.

"Eleyii ti a ri k'ẹyin ni ẹsẹ ẹnikan ti wọn ge.

O dabi ẹni pe lati ile iwosan to wa lagbegbe naa ni wọn ti ju ẹsẹ ọhún sinu idọti.

Àkọlé fídíò, Money Ritual: Ǹ kò le bèèrè

Nigba kugba ti a ba ri nkan bayii ni a maa n sọ fawọn ọlọpaa ati ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika.

Awọn ni wọn maa n sin iru oku bẹẹ.

Laipẹ yii ni a tun ri ibọn atọwọrọ meji, lẹsẹ k'ẹsẹ ni a sọ fun oludamọran pataki fun gomina lori ọrọ eto abo," Ayebakari ṣalaye.

Awọn eeyan tun n pọn igbọnsẹ sinu ọra:

Ọgbẹni Ayebakari tun ṣalaye pe ọpọ eeyan lo maa n pọn igbọnsẹ wọn sinu ọra ti wọn si maa ju sinu idọti.

O ni eleyii n ṣẹlẹ nitori ọpọ ilegbee ni ko ni ile igbọnsẹ.

"Ara awọn ipenija ti a maa n koju niyii lẹnu iṣẹ idọti kiko.

Oriṣiiriṣii idoti ni a maa n ko papọ, idọti adugbo, idọti ike, irin to ti bajẹ, idọti ile iwosan.

Ko yẹ ki a maa ko gbogbo rẹ papọ bi a ṣe n koo.

Àkọlé fídíò, Abeokuta murder

Baagi tó kún fun ayederu owo dọla:

Awọn ẹlẹyinju aanu kan maa n bun awọn oṣiṣẹ wa lowo lati mọ riri wọn.

Ọjọ kan tiẹ wa ti a ri dọla ninu baagi kan ninu idọti.

Ṣugbọn inu idọti naa ni a ju dola ọhún pada si tori awakọ akódọ̀tí lọjọ naa ni ayederu dọla lowo naa.

Ṣugbọn awọn to gbe owo naa lọ paarọ rẹ si mílíọ̀nù mẹjọ naira.

A maa foju ri ẹbọ ninu idọti:

Nigba mii a maa n ri ẹbọ ninu idọti.

Ọlọrun tí o n ṣọ wa ni ko jẹ ki aisan maa ṣe wa pẹlu oriṣiiriṣii nkan ti a maa n foju ri.

Nitori naa ni a fi ni ṣọọṣi nile iṣẹ wa.

Ẹni to ba si jẹ musulumi naa lanfaani lati ṣe ẹsin rẹ.

Pasitọ mẹrin ọtọtọ ni o wa ni ọfiisi wa ti wọn maa n gbadura fun wa