Abeokuta Ritual Killing: 'Colour Ghana Must Go' ló tú àṣírí Tọkọtayà náà níbi tí wọ́n kó ifún ọ̀rẹ́ ìyàwó tí wọ́n pa tà náà sí- Baale Leme
Omi ló wa loke ike naa, ko si nkan mii nibẹ ni ariwo ti ọkọ iyawo naa n pa fun wa nigba ti a fẹ tu iyara wọn wo- Baale Leme ni abeokuta ni ipinle Ogun
Se ẹ ranti Tokotaya ti wọn ba ifun eeyan ninu ike ninu iyara wọn ni agbegbe Abeokuta ni guusu Iwo oorun Naijiria?Afurasí tọkọtaya ta ẹ̀yà ara fún ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin náírà- Ọlọ́pàá
BBC Yoruba ti de ibẹ lati mu ohun to ṣẹlẹ gangan wa fun un yin ki onikaluku le kọ ẹkọ bi o ti yẹ.
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
- Makinde buwọ́lu Sẹ́nẹ́tọ̀ Lekan Balogun gẹ́gẹ́ bí Olubadan tuntun
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Oríṣìíríṣìí aṣọ aláràǹbarà láwọn òṣèré tíátà fi ṣe àyájọ́ ọjọ́ olólùfẹ́
Bawo ni ọrọ ṣe ṣẹlẹ gangan?
Alhaji Moshood Ogunwoolu to je Baale agbegbe Lemo ni Abeokuta lo ba BBC Yoruba sọrọ lori bi wọn ṣe ri oku naa lọna meji.
Baale naa ni pe ọkọ iyawo ti ọwọ tẹ naa sọ pe iṣẹ Babalawo ni oun n ṣe jẹun.
Okọ ilu ni pe apa ati aya ati ẹsẹ ti wọn ba ninu apo aromiyọ iko nkan pamọ si ti awọn kan n pe ni "Ghana Must Go" lẹgbẹ odo ni wọn ti kọkọ ri.
Baale naa ṣorọ ilẹ kun lori bi awọn Tokotaya yii ṣe ko ifun ati ẹya ara ọrẹ iyawo to ku naa pamọ sinu ike ti wọn pọn omi sii ati ipa ti awọn ara ile, ara adugbo ati ara abule naa ko lori iṣẹlẹ yii.,

Kini Oga ọlọpaa ri sọ si ọrọ naa?
Oga Olopaa Abimbola Oyeyemi naa ba BBC Yoruba sọrọ lori iṣẹlẹ naa.
O salaye ibi ti iṣẹ iwadii ti de bayii ati pe ijiya to tọ yoo jẹ awọn Tokotaya yii ni kete ti ẹjọ ba ti pari lori ọrọ naa.
Bakan naa lo gba awọn eeyan nimọran lati ma dagbere ibikibi ti won ba n lo lasiko yii nitori pe : Mo n bọ kii ṣe adireẹṣi ti eeyan le wa ẹni to sọnu si o.
- "A ti ṣetán láti gbógun ti ikú àìtọ́jọ́ tó ń pa àwa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì OAU"
- Kọmísánnà ọlọ́pàá ní London kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ torí ìkéde a kò nígbẹkẹ̀lé nínú rẹ mọ́
- Ọ̀pọ̀ àgbà òṣèré tíátà péjú sí Ede láti sin Tafa Oloyede déle ìkẹyìn
- Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
- Ìjọba Guinea-Bissau di ẹbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n rú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró
- Iṣẹ́ So-bàtà ní bàbá mi fẹ́ kí ń kọ́ ní Agbeni, kí ń to gba oko eré tíátà lọ - Iya Ibadan Sneh
- Ẹ dẹ́kun bíba ìjọba lórúkọ jẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun fèsì sí lẹ́tà Oluwo