Ogun Ritual murder: Ìjà ni tọkọtaya ní àwọn fẹ́ bá àbúrò mi àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ parí kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò - ẹ̀gbọ́n olóògbé

Oríṣun àwòrán, @Oyeyemi
Oriṣii iṣẹlẹ kayeefi lo gba igboro kan bayii.
Lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kàyéfì, à gbọ́ kọ hà ni ti àwọn tọkọtaya tí àwọn ọlọ̀pàá nawọ́ gán lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kejìlá, oṣù kejì, ọdún 2022 fẹ́sùn pé wọ́n bá ẹ̀ya ara ènìyàn tí wọ́n dé mọ́ inú ike nínú yàrá wọn.Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọtaya tó gbé ẹ̀yà ara ènìyàn pamọ́ sínú yàrá l'Ogun
Lẹyin ti iroyin ti gba igboro kan pe awọn ẹbi awọn ti ọrọ kan ti mọ wọn ti arabinrin Comfort si ti jade sita sọ pe aburo oun ni iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni BBC kan si awọn agbofinro ipinle Ogun.
Nígbà tí BBC Yorùbá kàn sí agbẹnusọ àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ní ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti mọ ẹni tí àwọn tọkọtaya náà dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò.
- A ṣì lè yanjú ọ̀rọ̀ Ukraine ní ìtùbí-ìnùbí - Russia
- Ọmọ ọdún 18 dèrò àtìmọ́lé lórí ẹ̀sùn pẹ ó gún akẹgbẹ́ lọ́bẹ pa
- Títí di àsìkò yìí, a kò tíì mọ̀ eèyàn ti òkú náà jẹ́ ṣùgbọ́n a ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ ìwádìí tó yẹ Ogá Ọlọ́pàá Ogun
- Barrister ló sọ mí di èèyàn ńlá - Ayinla Kollington
- Ki lo ṣokunfa ikọlu to n waye si ẹni to ba wọ aṣọ Sunday Igboho tabi Yoruba Nation n'Ibadan?
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá dárúkọ àwọn ọlọ́pàá mẹ́rin tó ń bá Abba Kyari ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé oògùn olóró
Oyeyemi ní àwọn ẹ̀yà ara náà ni àwọn ti gbé lọ fí ibi tí wọn yóò ti ṣe àyẹ̀wò láti si ìdí òdodo múlẹ̀.
Bákan náà ló fi kún òkú ènìyàn tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ ní agbègbè Leme náà ti wà ní yàrá ìgbókùpamọ́sí fún ìwádìí tó jinlẹ̀.

Oríṣun àwòrán, Others
Ìjà ni tọkọtaya ní àwọn fẹ́ bá àbúrò mi àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ parí kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò - ẹ̀gbọ́n olóògbé
Ọlọ́run má jẹ̀ẹ́ kí a rin àrìnfẹsẹ̀sí, ibi tí orí mi yóò bá ti sọre ni kí ẹsẹ̀ ó gbémi rè ní àdúrà tí kìí wọ́n lẹ́nu àwọn ènìyàn pàápàá ẹ̀yà Yorùbá.
Lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń bu omi tútù sọ́kàn ẹni pàápàá nípa pípa ènìyàn láìbìkítà ti ń mú kí àdúrà yìí tún máa gbẹnu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
- Wo ìdí tí ilé ẹjọ́ àgbáyé ṣé ní kí Uganda sàn $325m fún DR Congo
- "Ìná tó ń ṣe àkóso ojú pópó ló dá ọkọ̀ agbówórìn dúró, tí adigunjalè fi kọ lù ú"
- Ọlọ́pàá kánkan kò ku sùgbọ́n a pa ọkan ninu àwọn tó fẹ́ já ọkọ̀ agbówórìn gbà-Ọlọ́pàá
- Ìjọba Guinea-Bissau di ẹbi ìdìtẹ̀gbàjọba tó foríṣánpọ́n rú àwọn tó ń ṣe fàyàwọ́ oògùn olóró
- Ará àdúgbò dáná sun afurasí méji tí wọ́n bá orí èèyàn lọ́wọ́ wọn ní àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjà ọ̀dàn
- Ìjà abẹ́nú bẹ̀rẹ̀ lẹ́gbẹ́ NURTW l‘Eko, nǹkan kò fara rọ
Kini Molebi rẹ n sọ bayii?
Ẹ̀gbọ́n olóògbé tí wọ́n bá ẹ̀ya ara rẹ̀ nínú yàrá náà, Ife, Comfort ní láti ọjọbọ̀ tó kọjá ní àwọn ti ń wá olóògbé náà lẹ́yìn tó jáde nílé ní nǹkan bí aago mẹ́wàá sí aago mọ́kànlá òwúrọ̀.
Ó ní láti ìgbà yìí náà ni àwọn ti ń wá a, kódà àwọn ti lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá láti lọ kéde wíwá rẹ̀.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé Comfort, ó ní òun kò sí nílé nígbà tí àbúrò òun jáde nílé débi tí òun yóò mọ ibi tí ó lọ ṣùgbọ́n ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó wà níbẹ̀ nígbà tó gba ìpè láti ọdọ ẹnìkan lo sọ fún òun pé ìpè ló gbà.
Ó ní ọ̀rẹ́ ọ̀hún ní nígbà tó gba ipe náà, àyà rẹ̀ já, ó sì ní kí ló dé tí ẹni náà fi ń pè òun, tí òun sì sọ pé tí ọkàn rẹ̀ kò bá ti lọ kó má lọ.
Comfort fi kun pé nígbà tó sọ fún ẹni náà pé kó jẹ́ kí àwọn pàdé lọ́jọ́bọ̀ dípò ọjọ́rù tó pè é, ẹni náà sì fún un lésì pé òun fẹ́ rin ìrìnàjò lọ́jọ̀ kejì náà nítorí kó wá lọ́jọ́ náà gan an ni.
"Ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé ẹni tí ó pe òun fẹ́ bá òun àti ọ̀rẹ́kùnrin òun parí aáwọ̀ tó wà láàárín àwọn ni láti ìgbà náà ni àwọn ti kò si."
Báwo ló ṣe mọ̀ pé àbúrò òun ni wọ́n pa?
Comfort ní ará ilé ìjọsìn àwọn tó máa ń lọ tún ọ̀kadà ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí Ife ti ń ta Indomie ló pè mí pé wọ́n ti bá wa rí Ife, ó sì ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá ṣùgbọ́n òkú rẹ̀ ni òun bá.
Nígbà tó ń ṣàlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀, bàbá onílé náà ní àwọn ará ilé ló ta òun lólobó lórí òórùn tí wọ́n ń gbọ́ láti yàrá àwọn tọkọtaya náà.
Awọn wo ni ọwọ ọlọpaa tẹ bayii lori iṣẹlẹ naa?
Àjọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti nawọ́ gán tọkọtaya kan tó ń gbé ní ojúlé 72, MKO Abiola way, Leme ní ìlú Abeokuta fún ẹ̀sùn pé wọ́n ní ẹ̀yà ara ènìyàn nílé.
Àwọn tọkọtaya náà ni Kehinde Oladimeji ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì àti ìyàwó rẹ̀, Adejumoke Raji, ẹni ọdún márùndínlógójì.
Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi ní inú ike ńlá kan nínú yàrá àwọn tọkọtaya náà ní àwọn ti bá àwọn oríṣìíríṣìí ẹ̀yà ara ènìyàn.
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- U.S. yóò máa fún àwọn ọmo Nàìjíríà kan ní físà ìwé ìrìnnà láì ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò
- Àwọn nǹkan mẹ́ta tí a kò tíì mọ̀ nípa Covid-19 lẹ́yìn tí àrùn náà bẹ́ sílẹ̀ rèé
- Wo orílẹ̀èdè míì l‘Áfíríkà tí ìfipá gbàjọba tún ti ń rúgbó bọ̀
- Ìjọba Oyo gba adé lórí àwọn baálẹ́ àti Mogaji tí Ajimọbi sọ di ọba ní Ibadan
- Fásìtì yóò fí $250m gbára torí aṣemáṣe dókítà rẹ̀ pẹlu obìnrin
Oyeyemi ní àwọn tọkọtaya náà ní oníṣègùn làwọn àti pé àwọn ara náà tó jẹ́ ọwọ́, ọmú àti àwọn mìíràn ni ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Micheal, tó ń gbé ní Adatan gbe sí àwọn lọ́dọ̀.
Ó ṣàlàyé pé gbogbo ìgbìyànjú láti nawọ́ gán Micheal náà ló já sí pàbó bí àwọn afurasí náà kò ṣe mọ ilé rẹ̀ mọ̀.
Báwo ni wọ́n ṣe nawọ́ gán wọn?
Oyeyemi ṣàlàyé pé Baálẹ̀ Leme, olóyè Moshood Ogunwolu ló mú ẹjọ́ lọ sí àgọ ọlọ́pàá Kemta pé ọkùnrin kan, Pásítọ̀ Adisa Olanrewaju, tó jẹ́ alábàgbé àwọn afurasí náà, wá fi ẹjọ́ sun òun pé àwọn ń gbọ́ òórùn tí kò dára láti yàrá àwọn afurasí ọ̀hún.
Èyí ló mú kí DPO àgọ́ ọlọ́pàá Kemta ní kí àwọn ọlọ́pàá lọ ṣe àyẹ̀wò yàrá àwọn afurasí yìí níbi tí wọ́n ti bá àwọn ẹ̀ya ara náà nínú ike kan.
Kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà, Lanre Bankole ti wá pè fún títarí ẹjọ́ náà sí ẹ̀ka tó wà fún ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ náà (CIID) fún ìwádìí ìjínlẹ̀.
Kọmíṣọ́nnà náà jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ẹnikẹ́ni tó bá lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà yóò fojú winá òfin.
Ẹ ó rántí pé ní bíi ọ̀sẹ̀ kan sẹ́yìn ni wọ́n bá òkú ènìyàn kan tí ẹ̀yà ara kò pé ní agbègbè Leme.
Oyeyemi ní ìwádìí kò ì tíì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá ara òkú náà ni wọ́n yọ èyí tí wọ́n bá nínú yàrá àwọn afurasí yìí.




















