Uganda Conflic Role in DR Congo: Bí Uganda yóò ṣe san $325m fún DR Congo rèé

Oríṣun àwòrán, AFP
Wọn ti paṣẹ fun orileede Uganda pe ko san owo gba ma binu Miliọnu lọna okoolelọọdunrun ati marun dọla ($325m) (£240m) fun orilẹede Democratic Republic of Congo lori ikogunja ilẹ wọn.
Ileẹjọ agbaye to n gbọ ẹsun iwa ọdaran naa (ICJ) lo dajọ pe Uganda tapa si ofin to de ibaṣepọ orilẹede sirawọn, nigba to ko ogun wọ ilẹ DR Congo laarin ọdun 1998 si 2003.
Wọn ni Uganda ṣokunfa iku eeyan ẹgbẹrun mẹwaa si mẹẹdogun lagbegbe ila oorun Ituri.
Bẹẹ naa ni wọn ni iwadii fi han pe awọn ọmọogun Uganda ji goolu, diamond ati igi gẹdu nibẹ.
Biliọnu mọkanla dọla ni DR Congo beere lọwọ ile ẹjọ gẹgẹ bi owo gba ma binu ṣugbọn ileẹjọ wọgile awọn owo kan, ti wọn si ni ki wọn san owo ti ko to iye naa.
Agbekalẹ bi Uganda yoo se sanwo fun DR Congo ree:
Ile ẹjọ ICJ paṣẹ fun Uganda pe ki wọn san owo naa ni ipele marun un $65m laarin ọdun 2022 si 2026.
Wọn yoo san akọkọ owo naa ni oṣu Kẹsan ọdun yii.

Oríṣun àwòrán, AFP
Uganda ti ṣaaju sọ pe ọpọ biliọnu ti DR Congo n beere yii le ṣakoba fun ọrọ aje oun.
Ileẹjọ sọ pe owọ tawọn yoo bu fun wọn bii owo gba ma binu, ko ni kọja agbara wọn lati san.
Ohun ti wọn yoo lo owo gba ma binu $325m yii ṣe ni iwọnyii:
- $225m fun ipalara fawọn eeyan
- $40m fun ipalara si dukia
- $60m ipalara fun alumọni orileede naa ti wọn ji wa
Nkan ti idajọ naa sọ:
Ileẹjọ sọ ninu idajọ rẹ pe ''owo gba maa binu taa ni ki wọn san fun DRC ṣafihan iru ijamba to ṣẹlẹ sawọn eeyan ati dukia, to fi mọ adugbo nipa bi Uganda ṣe tapa si ofin to de orileede kọọkan lagbaye''
Ni ọdun 1999 ni DR Congo kọri si ile ẹjọ fun ikogunjalu ti alabagbe rẹ Uganda ṣe si.
O fẹsun kan awọn ọmọ ogun Uganda pe wọn hu iwa ifiyajẹniyan ati jiji alumọni orileede wọn.
Ọpọ awọn ikọ agbebọn lo ti n ṣe akoba fun awọn eeyan agbegbe ti alumọni psi laimọye ọdun ni DR Congo.
Ni ọdun 1990 soke awọn ọmọ ogun Rwanda ati Uganda kogun ja DR Congo pẹlu iranwọ awọn ọmọ ogun ọlọt able.
Erongba wọn ni pe wọn fẹ yẹ aga nidi ijọba to wa loriu alefaa.
Awijare wọn nigba naa ni pe awọn kogun wọ ilẹ DR Congo ki ogun abẹle to n waye nibẹ ma baa tan de ọdọ wọn.
Kini Uganda wa sọ nipa idajọ yi?
Idajọ yii ko tẹ Uganda lọrun, to si ni idajọ naa ko ṣe deede.
Agbẹjọro agba fun Uganda, Kiryowa Kiwanuka beere pe ki lo de ti wọn fi da awọn ọmọogun Uganda yọ lọtọ, nigba to ṣe pe awọn ikọ miran naa lọwọ ninu ikọlu ọhun.
Ko sọ boya Uganda yoo san owo gba ma binu naa ṣugbọn o ni awọn yoo ṣi tẹsiwaju lati jiroro pẹlu ijọba DR Congo lati yanju ọrọ naa.
Idajọ ile ẹjọ agbaye ko ni ọrọ a n ṣipẹ ninu ṣugbọn ile ẹjọ naa ko ni aṣẹ lati fidi idajọ yii mulẹ.

















