DR Congo Meningitis: Àrùn yínrùnyínrùn bẹ́ sílẹ́ ní DR Congo, àjọ WHO ní ìgbàgbọ́ àwọn èèyàn pé 'àwọn àjẹ́' ló wà nídí rẹ̀ ń dènà ìtọ́jú

Onimọ ilera kan nibudo iwadi ijinlẹ.

Oríṣun àwòrán, Who

Iroyin kan n sọ pe ajakalẹ arun yinrunyinrun ti bẹ silẹ lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede DR Congo, bẹẹni awọn eeyan ileto ti arun naa ti n ṣọṣẹ n sọ pe awọn ajẹ atawọn ẹgbẹ ẹlẹyẹ lo n da arun naa silẹ.

Gẹgẹ bi ohun ti ajọ ilera lagbaye, WHO sọ fun BBC, ọpọlọpọ iṣoro lawọn ajọ ilera atawọn akọṣẹmọṣẹ lati wa ọwọ ajakalẹ arun naa bolẹ pẹlu igbagbọ awọn eeyan agbegbe naa pe awọn ajẹ ati ẹlẹyẹ ni wọn wa nidi bi arun yinrunyinrun naa ṣe n pọ si nibẹ.

Ni bayii, eeyan ọgọfa ni ajakalẹ arun naa ti ran lọ sọrun, bẹẹni nkan bi ọgọrun miran si tun ti wa nileewosan kaakiri fun itọju.

Iha ti awọn eeyan agbegbe naa kọ si arun naa kun ara ohun to fa iku ọwọọwọ nipasẹ ajakalẹ arun naa.

Gẹgẹ bi ajọ WHO ṣe sọ, dipo ki ọpọ awọn ti arun naa ba o tọju rẹ bi o ti tọ, nṣe ni awọn eeyan naa n sa lati ibudo kan si ekeji pẹlu ireti pe arun naa ko ni tẹle wọn.