Anti-grazing bill: Miyetti Allah kéde iye mílíọ̀nù tí wọ́n fẹ́ máa ta màálù kan tí ìpínlẹ̀ Eko bá fòfin de ìdẹranjẹko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ darandaran Miyetti Allah ti sọ iye ti wọn yoo maa ta maalu kan ti ijọba ipinlẹ Eko ba fi le fofin de idẹranjẹko ni gbangba.
Akọwe ẹkun iwọ oorun guusu fun ẹgbẹ Miyetti Allah, Mai-Kudu Usman lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Lọjọ Aje ọjọ keje oṣu kẹsan an ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko fi abadofin ma fẹranjẹko ni gbangba si igbimọ to n ri si eto ọgbin.
- Wo ìgbésẹ tí Sunday Igboho fẹ́ gbé báyìí lórí àwọn agbẹjọ́rò Cotonou tó ní wón ń gba N4m sí N3m lọ́wọ́ òun
- Ọwọ́ tẹ afurasí bàbá ẹni ọdún 64 tó fi ìpá bá ọmọ ọdún méjì lòpọ̀
- Kí ló mú kí gbogbo títì dá páropáro ṣáájú àbẹ̀wò Ààrẹ Buhari sí ìpínlẹ̀ Imo?
- Àjọ DSS fi ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí kan olùrànlọ́wọ́ Sunday Igboho méjì tó kù sí àhámọ́
- Àjọ DSS fi ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí kan olùrànlọ́wọ́ Sunday Igboho méjì tó kù sí àhámọ́
- Bí mo bá fún obìnrin lóyún báyìí, mi ò ní kọ oyún náà, ṣùgbọ́n… - Bobrisky
- Àwọn jàndùkú agbébọn jí òṣìṣẹ́ ààrẹ Nàìjíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo mẹ́ta lọ
Usman parọwa si ipinlẹ Eko lati ran awọn darandaran lọwọ nitori dida ọgba ẹranko silẹ yoo la owo lọ.
O ni ọsin ẹran maalu loju kan naa le mu ki maalu kan to miliọnu meji naira.
Bakan naa ni Usman tun rọ ijọba lati ṣe iranwọ owo fawọn ọlọsin ẹran maalu loju kan naa.
''A ti ṣe adehun pẹlu awọn eeyan ipinlẹ kan lati ma sin maalu loju kan naa.
A jọ gba wi pe a maa forukọ silẹ gbogbo awa darandaran.
Awa Fulani maa n lọ lati ibikan si ibomiran ni, a mọ lootọọ ni awọn ọdaran Fulani wa ti wọn n da wahala silẹ.
A fẹ ki ijọba fun wa ni anfaani lati ba awọn eyan wa sọrọ.
A ti sọrọ pẹlu awọn ti ọrọ kan nipinlẹ Ondo, Ekiti ati Oyo lori ọrọ yii,'' Usman lo sọ bẹẹ.
Bakan naa, alaga awọn alapata nipinlẹ Eko, Alhaji Alabi Bamidele Kazeem, beere iranlọwọ ijọba fawọn daran daran.
O ni owo nla ni yoo maa na wọn lati maa sin ẹran maalu loju kan naa.












