Sunday Igboho aides: Àjọ DSS fi ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí kan olùrànlọ́wọ́ Sunday Igboho méjì tó kù sí àhámọ́

Awọn afurasin naa

Ajọ ọtẹlẹmuyẹ, DSS, ti fi awọn ẹsun to ni i ṣe pẹlu igbesunmọmi kan oluranlọwọ Sunday Igboho meji to ku si ahamọ wọn.

Lasiko igbẹjọ to waye ni ile ẹjọ giga ijọba apapọ nilu Abuja ni ajọ naa ti ka awọn ẹsun ọhun lẹyin oṣu meji ti wọn ti mu awọn eniyan naa ati awọn mẹwaa miran.

Ninu iwe ipẹjọ ti wọn pe ni FHC/ABJ/CR/305/2021 ni agbẹjọro ajọ DSS, S.M Bello ti fi ẹsun igbesunmọmi marun-un kan Noah Oyetunji ati Amudat Babatunde, to jẹ obinrin.

Ajọ naa fi ẹsun kan Oyetunji pe awsn ba awọn nkan ija oloro fun igbesunmọmi lọwọ rẹ.

Ni ti obinrin naa, Amudat Babatunde, wọn fi ẹsun kan an pe o polongo igbesunmọmi lori ayelujara Facebook rẹ.

Amọ nigba to fesi si awọn ẹsun naa, agbẹjọro awọn afurasi ọhun, Pelumi Olajengbesi sọ pe awsn ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ, to si tun jẹ nkan itiju.

Ọjọ diẹ sẹyin ni ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS tu mẹwaa lara awọn afurasi mejila naa silẹ, lẹyin ọgọta ọjọ ti wọn ti wa ni ahamọ rẹ.

Eyi waye lẹyin ọpọ ọjọ ti ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki wọn o gba beeli awọn eniyan naa.

Ọjọ kinni, oṣu Keje, ọdun 2021 ni wọn ko awọn eniyan ọhun lasiko ti wọn kọlu ile Sunday Igboho to wa ni agbegbe Soka, nilu Ibadan.

Eeyan meji ni iroyin sọ pe wọn yinbọn pa nibẹ.