Miyetti Allah ń fẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣòfin lòdì sí ẹran dídà láàrín ìlú

Buhari, a fẹ́ kí o dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣe òfin tako fífi ẹran jẹko láàrín ìgboro - Miyetti Allah

Ẹgbẹ awon darandaran ni Naijiria, Miyetti Allah, ti ke si ijọba apapọ lati bẹgi dina igbesẹ awọn gomina lati ṣe ofin to lodi si fifi maalu jẹko laarin igboro.

Akọwe ẹgbẹ naa, Saleh Alhassan, lo kede bẹẹ nibi ipade awọn akọroyin kan niluu Abuja.

O ni ofin naa yoo da omi alaafia to ti wa laarin Miyetti Allah atawọn eeyan igberiko lati ọpọ ọdun sẹyin ru.

Àkọlé fídíò, Oba Ogboni: Bí ìwọ́de Yoruba Nation bá tún wáyé, màá bá wọn kópa níbẹ̀

Alhassan sọ pe "A fẹ ki ile igbimọ aṣofin agba ati Aarẹ Naijiria gbẹsẹle igbesẹ awọn gomina kan lati fofin de awọn darandaran lẹnu iṣẹ oojọ wọn pẹlu ofin buruku ti wọn fẹ fi de fifi maluu jẹko laarin ilu."

"O yẹ ki ijọba apapọ da ileeṣẹ ti yoo maa ri si ọrọ ẹran ọsin ati ẹja sinsin gẹgẹ bo ṣe wa lawọn orilẹ-ede mii nilẹ Afrika, o si yẹ ki Naijiria le wa awọn ọna lati dojukọ awọn iṣroro ti ayipada oju ọjọ n mu ba awọn darandaran."

Alhassan sọ pe ofin tuntun ti awọn gomina naa dawọle yoo sọ awọn darandaran atawọn ogunlọgọ awọn to n fi ẹran ọsin jẹun sinu iṣẹ ti ko ṣe fẹnusọ.

Miyetti Allah ń fẹ́ kí ìjọba àpapọ̀ dẹ́kun àwọn gómìnà tó ń ṣòfin lòdì sí ẹran dídà láàrín ìlú

Oríṣun àwòrán, Miyettti

Adari awọn Miyetti Allah naa tun ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati ṣe atungbeyẹwo awọn ibi ti wọn ti ya sọtọ tẹlẹ fun itọju ẹran ọsin ni Naijiria, ko si kọ ibi ti wọn ti yoo ti maa tọju awọn ẹran ọsin ni ẹkun idibo kọọkan ni Naijiria.

Lẹyin naa lo ke si ile igbimọ aṣofin agba lati gba awọn darandaran naa silẹ nipa fifi ọwọ si ofin idasilẹ awọn ibudo ẹran ni Naijiria.

Adari Miyetti Allah ọhun tun tọka si iwe ofin kan ti ajọ AU ati ECOWAS buwọlu to rọ mọ ẹran dida laarin awọn orilẹ-ede nilẹ Afrika.

O ni ti ijọba Naijiria ba ṣe agbekalẹ irufẹ ofin bẹ labẹle, ko ni si pe awọn atọhunrinwa adaran Fulani wa n pa eeyan bi ẹni pa ẹran ni Naijiria.

Miyetti Allah lo n sọ ọrọ yii lede lẹyin oṣu mẹrin ti awọn gomina ni iha guusu Najiria fofin de fifi ẹran jẹko laarin igboro.

Awọn gomina ọhun pade niluu Delta, nipinlẹ Asaba, nibi ti wọn ti ke si Aarẹ Buhari lati ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lori ọrọ naa.

Lẹyin oṣu meji si asiko naa ni wọn fẹnuko lati ṣe ofin lodi si dida ẹran laarin igboro lawọn ipinlẹ wọn lọna ati fopin si ipakupa ti awọn ọdanran Fulani n pa awọn eeyan wọn.