Bobrisky: Kí ló le mú kí Bobrisky fẹ́rẹ̀ bú sí ẹkún níbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/Instagram
Yoruba ni inu ẹni kii dun, ka pa mọra, gbogbo ẹni ti ọjọ ibi ba si ba laye, dandan ni ko se ọpẹ.
Boya eyi lo mu ki gbajumọ ọkunrin to n mura bi obinrin, Olanrewaju Idris Okuneye, ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky, se sajọdun ọjọ ibi ọgbọn ọdun to dele aye lọna ara ọtọ, to si dun, to larinrin.
Ọjọ Isẹgun, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 si ni Bobrisky ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi naa nilu Eko, ti aye gbọ, ti ọrun si mọ pẹlu.
- Bobrisky@30: Àpótí òní páálí láwọn àlejò yóò fí wọlé síbi àpéjẹ̀ Bobrisky
- Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
- Bobrisky fi àwòrán tuntun léde lẹ́yìn tó parí iṣẹ́ abẹ ìdí tó ṣe
- Kò bá wù mí kí n padà sí àwọ̀ tí Ọlọ́run dá mi, wàhálà ni ara bíbó - Bobrisky
- Mò ṣì ń ṣépè lọ́wọ́lọ́wọ́ fáwọn ọ̀rẹ́ tó ní kí ń ṣiṣẹ́ abẹ ìdí - Bobrisky
- Mo fẹ́ di obinrin to dára júlọ lágbàyé-Bobrisky
- Bobrisky sọ̀rọ̀ sókè lórí ìdí tí kò fi kópa nínú àwẹ̀ Ramadan tó ń lọ lọ́wọ́
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
Fun igba akọkọ lẹyin to ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgbọn ọdun rẹ naa, Bobrisky ti wa bọ sita lati salaye iye owo to na sori ayẹyẹ naa ati awọn eeyan jankan jankan lorilẹede Naijiria to gba lalejo.
Ọlọjọ ibi naa, to ti kọkọ lọ sisẹ abẹ idi loke okun lati le se idi balabala ko to di ọjọ ayẹyẹ naa kede pe oniruuru gbajumọ, olorin, elere ori itage, ati awọn miran lo wa nibẹ.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/Instagram
Amọ ọkan lara awọn agba akọrin Fuji nni, Alhaji Wasiu Ayinde Marshall, ti ọpọ eeyan mọ si Kwam 1 si lo kan ilu si ọlọjọ ibi ati awọn eeyan nibadi nibi ayẹy naa.
Nigba to n kede iye owo to na lati fi se ọjọ ibi naa, miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500m) ni ilumọọka ọkùnrin to n pe ara rẹ ni obìnrin ọhun sọ pe oun na sori ayẹyẹ naa.
Saaju lo ti kọkọ kede pe miliọnu méje Naira ni oun fi ya fọto imurasilẹ (photo shoot) fun ọjọ ibi naa.
Ọmọ ọlọjọ ibi sọ pe diẹ lo ku ki oun busẹkun ni alẹ ọjọ ayẹyẹ naa, nigba ti oun ri ero to wa lati yẹ oun si.
O ni ọkùnrin ati obinrin pataki lawujo, àwọn Ọga ileesẹ, ati awọn ilumọọka oloselu lo peju sibẹ.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/Instagram
Bẹẹ ba si gbagbe, saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe apoti onipaali ti eroja lotisirisi kun inu rẹ, ti owo rẹ to miliọnu kan naira ni Bobrisky fi se iwe apejẹ lati fi pe awọn alejo wa sibi ayẹyẹ ọjẹ ibi rẹ naa.
Bakan naa ni awọn asọ ti ọlọjọ ibi naa wọn jẹ oju nigbese, to si daju pe owo nla ribiribi lo ra awọn asọ igbalode naa ni ti ibilẹ ati ti oloyinbo.
Koda, se ni asọ Kaba alawọ wura to wọ ni ọjọ ibi rẹ naa n kọna yanranyanran, ti awọn okuta onidan si to si ara asọ naa jingbinni.
Bakan naa ni akara oyinbo ti Bobrisky ge fun ayẹyẹ ọjọ ibi naa ga pupọ, to si to orisi mẹta, ti wọn jẹ olowo iyebiye.
Niwọn igba to si jẹ pe owo la fi n peena owo, owo nla ni Bobrisky pa lati ipasẹ ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ naa, gẹgẹ bo se gbe fidio kan jade loju opo ayelujara rẹ́.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky222/Instagram


















