Yollywood Round up: Àpótí òní páálí láwọn àlejò yóò fí wọlé síbi àpéjẹ̀ ọjọ́ọ́bí Bobrisky

Aworan Bobrisky

Oríṣun àwòrán, Instagram/bobrisky222

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja obinrin to n mura bi ọkunrin, Idris Okuneye ti ọpọ eeyan mọ si Bobrisky ti kede ipalẹmọ fun ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ.

Bobrisky, ninu video tuntun to gbe soju opo Instagram rẹ salaye pe agba akọrin Fuji nni, King Wasiu Aynde Marshal, ti awọn eeyan tun mọ si Kwam 1, ni yoo kọrin nibi ayẹyẹ ọjọ ibi naa.

Bobrisky, ẹni ti yoo pe ọgbọn ọdun ni ọgbọnjọ osu Kẹjọ ọdun 2021 la ri ninu fidio naa, to n gbe apoti onipaali kan fun Ọba orin Wasiu Ayinde.

Ninu Fidio naa ni Bobrisky ti ni "@kingwasiuayindemarshal yoo wa nikalẹ lati kọrin fun awọn alejo mi lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi ọgbọn ọdun mi.''

''O maa lagbara gan ni, ẹ jẹ ki eto kika ọjọ ayẹyẹ bẹrẹ lati oni lọ, ka le mọ iye ọjọ to ku.''

Oniruuru ipalẹmọ si ni Bibrisky ti se nipa ayẹyẹ ọjọ ibi naa, laipẹ yioi la ri to gbe paali kan to kun fun iwe ipe sibi ayẹyẹ naa sori ayelujara.

Aworan oti ninu paali

Oríṣun àwòrán, Instagram/bobrisky222

Lara awọn eroja to wa ninu apoti iwe ipe sibi apejẹ ti yoo fi ransẹ si ikọọkan alejo to ba pe ni igo ọti waini kan, ororo itura oloorun didun, ife ọti waini to ni awọ goolu ati suti Sokoleti pẹlu ododo Rose funfun.

Awọn eroja yii si ni wọn fi asọ fẹlifẹti alawọ buluu we, ti Bobrisky si ni ẹnikẹni to ba ri apoti naa gba, ni o jẹ alejo pataki oun.

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Mo faramọ́ àtúntò 'Restructuring' tí kò lọ́wọ́ ìṣèlú nínú- Oba Ahmed Adeku

Iya Osogbo fẹsẹ rajo@92

O ti to ọjọ mẹta ti awọn ololufẹ gbajugbaja osere tiata nii Grace Oyin-Adejobi ti ọpọ mọ si Iya Oshogbo.

Niṣe lo jẹ ohun idunnu bi oṣere tiata Toyin Adegbola Toyin Tomato ṣe gbe mama soju iran awọn eeyan pada ni Instagram.

Aworan Toyin Tomato ati Iya Oshogbo

Toyin Tomato fi fọnran fidio ibi tawọn eeyan ti n kọ orin yẹ Iya Oshogbo si fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi wọn.

Mama Grace Oyin Adejobi to ti sinmi nidi ere tiata lati nkan bi ọdun meloo kan sẹyin pe ẹni ọdun mejilelaadọrin loke eepẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ifoti to gbona lo ma je to ba misbehave.

Ọrọ ti Sola Sobowale,Laburu fi n kilọ fun Debo Macaroni ati Mummy wa ree loju opo Instagram.

Ẹ ma foya kii ṣe ifọti tootọ bi kii ṣe pe awọn mẹtẹta jijọ kopa ninu fọnran fidio awada kẹrikẹri kan to jade laarin ọsẹ.

Aworan Macaroni ati

Oríṣun àwòrán, Instagram@mrmacaroni

Awọn ipa kogberegbe ni Sola Sobowale maa saba ko lagbo oṣere tiata amọ bi aaye ba yọ silẹ o maa n bawọn kopa ninu awọn ere awada lẹẹkọọkan.

@mrmacaroni naa kuku fi esi awada da Sobowale lohun bayi pe