Ife Modakeke crisis: Ìpànìyàn tó wáye ni abúle Toro kìí ṣe ìjà láàrín Ife ati Modakeke - Ooni Ile Ife

Oríṣun àwòrán, Ooniadimulaife/instagram
Ààfin Ọọniriṣa ti Ile Ife Ọba Adewusi Enitan Ogunwusi, ọjaja keji, ni ibanujẹ ọkan lo jẹ lati gbọ nipa bi awọn agbẹ marun se padanu ẹmi wọn ni abule Toro ni Ile-Ife.
Yatọ si pe kabiyesi bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ aburu naa, kabiyesi ti tete fi ọrọ naa to awọn agbofinro ati awọn ẹsọ alabo miiran leti ti wọn si gbe igbesẹ ni kiakia.
Ninu atẹjade ti adari iroyin ni aafin Ọọni Moses Olafare fọwọsi lo ti ṣalaye naa.
O ni pe, bi o tilẹ jẹ pe awọn kọlọrọsi eniyan kan n gboiyanju lati so iṣẹlẹ naa mọ wahala to wa laarin Ife ati Modakeke latẹyin wa sugbọn ọrọ ko ri bẹẹ.
Olafare ni aafin fi n da ara ilu loju pe iṣẹlẹ naa ko niṣe pẹlu Ife ati Modakeke bi ko se iṣẹ awọn ọdaran pọnbele ti ọwọ ofin kò si ni pẹ tẹwọn.
Ninu atẹjade naa Olafare ṣalaye pe gbogbo eniyan lo mọ pe olrilede Najiria n koju ọrọ ewto abo to mẹhẹ bi awọn agbegbe miiran lagbaye, sugbọn igbagbọ ni pe gbogbo rẹ yoo di afiẹyin ti eegun n fisọ laipẹ pẹlu ifọwọsọpọ ara ilu.
O ní ọpọ lo n gbiyanju lati sọ ọrọ naa mọ ẹlẹyamẹya lati gbe oju awọn agbofinro kuro lara awọn ọdaran to ṣiṣẹ ibi naa.
agbẹnusọ kabiesi lasiko to n gboriyin fun ijọba ati awọn eleto abo to fi mọ ọlọpaa, awọn ọtẹlẹmuyẹ, awọn soja ati awọn ọlọdẹ ti wọn tete dikde si ọrọ naa láti mu alafia jọba lawọn ilu gbogbo.
Ooni rọ gbogbo awọn ara ilu lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ ni irọwọrọsẹ, nitori awọn oniṣẹ ibi naa kii ṣe asoju ipinlẹ ilu kankan

Oríṣun àwòrán, other
Gómìnà Osun, kọmíṣọ́nnà ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ sókè lórí wàhàlà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ife àti Modakeke lọ́jọ́ Ẹtì
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ti ke sawọn eeyan agbegbe Ifẹ ati Mọdakẹkẹ lati maṣe fi aye gba awọn kọlọrọsi janduku laarin wọn lati da wahala silẹ nibẹ.
Ipe naa n waye pẹlu bi ikayasoke oun ipaya ṣe gbode kan ni ilu Ifẹ ati Mọdakẹkẹ lọjọ Ẹti lẹyin ti awọn oniṣẹ ibi kan ṣeku pa eeyan marun un ti ọpọ funra si pe wọn jẹ agbẹ nilu Mọdakẹkẹ.
Ijọba ipinlẹ Ọṣun ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna feto iroyin, Arabinrin Funkẹ Egbemode fi sita lo ti sọrọ.
O ṣalaye pe ipade kan ti waye laarin awọn alaṣẹ ijọba nipinlẹ naa atawọn alaṣẹ ileeṣẹ aalabo gbogbo nibẹ nibi ti wọn ti gbe ọrọ wahala to suyọ ni ifẹ ati Mọdakẹkẹ.
- Ìkáyàsókè ní Ife, Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún
- Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
- Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Modakeke àti Ile Ife
- Kábíyèsí Ooni ti forí jin Sunday Igboho lẹ́yìn tó túúbá- Ààfin Ile Ife
- Kílódé tí Ọọni Ife, Oba Ogunwusi kò fi gbọdọ̀ rí ọmọ rẹ̀ tuntun ti Olorì Naomi bí títí di bíi ẹ̀yìn oṣù mẹ́fà?
- Kà nípa ibi tí wọ́n bí Àrẹ̀mọ tuntun Ọọ̀ni Ife sí, àti orúkọ tó ń jẹ́
O fi kun un pe gomina ipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla funrarẹ ti pe Ọọni ti ilu ile Ifẹ, Ọba Ẹnita Adeyẹye Ogunwusi, Ọjaja keji ati Ogunṣua ti ilu Mọdakẹkẹ, Ọba Moses Oyediran Ọladẹjọ ti awọn mejeeji si ti fi daa loju pe omi alaafia laarin ilu mejeeji yii yoo pada toro.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọsun pẹlu ti ṣalaye pe igbesẹ ipana aawọ ti nlọ lọwọ lati ọjọ Ẹti ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
Ninu atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun , SP Yẹmisi Ọpalọla fi sita lo ti sọrọ.
Kọmiṣọnna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, Ọlawale Olokode ni awọn iroyin kan ti lu si ileeṣẹ ọlọpaa lọwọ ti yoo ṣe okunfa mimu awọn oniṣẹ ibi naa ni kiakia.
















