Ife Modakeke clash: Wàhálà bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ife àti Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún lọ́jọ́ Ẹtì

Oríṣun àwòrán, other
Iroyin lati ipinlẹ Ọṣun n sọ pe nnkan ko rọgbọ bayii laarin agbegbe ile Ifẹ ati Mọdakẹkẹ ni ipinlẹ naa lẹyin ti wọn ri oku awọn eeyan kan ti wọn pa lọna oko wọn.
Gẹgẹ bi awọn iroyin lati agbegbe naa ṣe sọ iṣẹlẹ buruku naa ṣẹlẹ ni nnkan bii agogo meje owurọ ọjọ Ẹti lagbegbe Toro ni Mọdakẹkẹ nigba ti awọn eeyan naa n lọ si oko wọn.
- Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
- Láàrín ọdún méjì ₦3 bílíọ̀nù làwọn ajínigbé ti gbà nílẹ̀ Yorùbá, èèyàn 200 ni wọ́n sì ti pa- Gani Adams
- Òpin ti dé bá ọjà títà àti títọọrọ báárà lójú pópó - ìjọba ìpìnlẹ̀ Eko
- Ẹgbẹ́ ALGON fún àwọn òṣìṣẹ́ NIS ní ọ̀jọ́ kan láti kúrò láwọn káńsù lórí ìkọlù alága ìjọba ìbílẹ̀ n'Ibadan
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla fi idi iroyin naa mulẹ fun BBC News Yoruba to si ni kọmiṣọna ọlọpaa nibẹ, Ọgbẹni Ọlawale Olokode ti paṣẹ kawọn ikọ ọlọpaa kogberegbe o lọ si agbegbe naa lati pẹltu si aawọ naa.
Iroyin sọ pe bi awọn ara ilu Mọdakẹkẹ ṣe gbọ iroyin naa ni awọn pẹlu ti mu ija lati koju ẹnikẹni to ba wa nidi ajalu naa.








