Lagos bans street hawking: Ìjọba ìpìnlẹ̀ Eko fòfin de ọjà títà àti títọọrọ báárà lójú pópó

Oríṣun àwòrán, Polley Nina
Ijọba ipinlẹ Eko ti ṣagbakalẹ igbimọ kan ti yoo fopin si ki kiri ọja laarin oju popo atawọn to n tọrọ baara nipinlẹ naa.
Ijọba Eko sọ pe awọn gbe igbesẹ yii nitori awọn adigunajle to maa n fara pamọ sabẹ irufẹ ọja tita tabi agbe lati lo ọna ẹburu ja awọn araalu lole.
Ikede igbimọ tuntun naa lo waye nibi ipade awọn akọroyin kan ti kọmiṣona fun ọrọ awọn ọdọ ati idagbasoke awujọ, Olusegu Dawodu, ṣe onigbọnwọ rẹ, eyii to waye ni Alausa.
- Ara mi bó fẹ́lẹ-fẹ̀lẹ lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ immigration lù mí mọ́ ọfíìsì mi - Alaga Ibadan North
- Bí àwọn ọmọ Yoruba bá ní ìbọn láti dáàbò bo ara wọn báyìí kò burú - Afenifere, YCE
- Ṣé mo jọ ẹni tó gba Benin Republic sá kúrò ní Nàìjríà ni? Lai Mohammed fèsí sí ìróyín pé Ó yọ́ kẹ́lẹ́ kúrò ní Nàìjíríà
- Wo àìsàn tí Ààrẹ Nààijíríà tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ń bá fínra láti ọdún 35 sẹ́yìn
- Àwọn àwòrán tó jojú ní gbèsè réè láti Akure níbi tí wọ́n tí n ṣé ọdún Ahérégbé àti Amólè
Dawodu ni wọn gbe igbimọ naa kalẹ lati kapa iwa ọdaran nipinlẹ Eko, eyii ti awọn kọlọrọsi kan n wu labẹ asia pe awọn taja tabi tọrọ baara.
O ni igbimimọ naa yoo bẹrẹ iṣẹ laipẹ lati fopin iwa idigunjale bẹẹ.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn n fopin si ki kiri ọja laarin oju popo nitori iroyin ti awọn gbọ pe pupọ lara awọn onibara atawọn ọlọja bẹẹ lo ni oniruru ohun ija oloro lara wọn.
O ni "Ijọba yoo ṣe ọpọ itaniji lawọn ileeṣẹ iroyin ki awọn eeyan le mọ igbesẹ ti ijọba n gbe lori ọrọ naa."
Dawodu gba awọn olugbe ipinlẹ Eko nimọran lati maa ko awọn owo tabi dukia wọn lọ sile awọn ọmọ alaini iya tabi opo nibi ti wọn yoo ti lo owo naa bo ṣe yẹ ti ba fẹ fi ṣe saraa.
Ninu ọrọ rẹ, "Titọrọ baara laarin adugbo kii ṣe ohun to yẹ ki a gba laaye lawujọ wa, bẹẹ naa ni tita ọjsa loju popo."
Kọmiṣọna ọhun fi kun pe igbesẹ awọn ko lodi si ofin ipinlẹ Eko ti wọn gbe kalẹ lọdun 2015.
- Ìpàdé ikọ̀ Amotekun pẹ̀lú àwọn aládúgbò ọmọ ọdún 15 tí wọ́n yìnbọn pa ní Mokola, ohun tí a gbọ́ níbẹ̀ nìyí
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun pàṣẹ kí ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí ikú èèyàn méje nínú ẹbí kan
- Fadá wọ gàù torí pé ó 'kiss' akẹ́kọ̀ọ́bìnrin mẹ́ta lọ́jọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde
- Èyí lohun tí Amòfin àgbà Nàìjíríà, Malami sọ níléẹjọ́ lónìí nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lu Fulani àti ìkọlù tó wáyé nílé Igboho
O ṣalaye pe igbese yii wa ni ibamu pẹlu ori 157, ati abala kinni ofin ipinlẹ Eko.
Lasiko to n sọrọ nibi ipade ọhun, kọmiṣona ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu sọ pe "Opin ti de ba ọja tita loju popo nipinlẹ Eko."
Odumosu ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fọwọsowọpọ pẹlu ijọba lati ri daju pe asiko awọn kọlọrọsi a lọ kolohun kigbe di ohun itan ni ipinlẹ Eko.
- Gómìnà ìpínlẹ̀ kan rèé tó ní kí aráàlú ó lọ ra ìbọn láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn agbébọn
- "Ìgbẹ̀yìn Naijiria yóò burú ju ti Afghanistan lọ tíjọba kò bá dẹ́kun ẹlẹ́yàmẹ̀yà"
- Oní Típà tó bá ta yanrìn ní iye owó tí a kò fọwọ́ sí yóò fojú balé ẹjọ́ - Ijọba ìpínlẹ̀ Ondo
- Ó ṣeéṣe kí adájọ́ míràn buwọ́lu ìwé béèlì àwọn méjìlá tí DSS mú nílé Igboho lónìí
- Àlàyé rèé lórí ìdí tí ọlọ́pàá Cotonou ṣe kọ́kọ́ fi ẹ̀wọ̀n so Sunday Igboho ní àhámọ́













