Ondo Blocks price hike: Búlọ́kù N200 to di N400 ní ìpínlẹ̀ Ondo fẹ́ mú kí ìjọba àtàwọn olówò búlọ́kù tutọ́ sójú ara wọn

Bulọọku ikọle

Oríṣun àwòrán, Sunshine Truth

Ijọba ipinlẹ Ondo ti paa laṣẹ fawọn awakọ tipa atawọn to n ṣe bulọọku ikọle lati owo yẹpẹ ati bulọọku si iye to wa tẹlẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe wọn ti owo bulọọku lati N200 ati N300 lọ si N300 ati N400 lori bulọọku ''6'' ati ''9.''

Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn awakọ tipa naa ṣe afikun owo yẹpẹ pẹlu idaji iye ti wọn n ta tẹlẹ.

Oludamọran pataki fun Gomina ipinlẹ Ondo lori iṣẹ ode ati ọgbọn inu, Ọgbẹni Doyin Odebowale lo kede aṣẹ ijọba ipinlẹ Ondo ọhun.

Odebowale ni ijọba fun awọn awakọ ati atawọn onibulọọku di ọjọ Aje to n bọ lati ṣe atunṣe.

O ni ijiya to tọ ni ijọba yoo fi jẹ ẹnikẹni to ba kọ eti ikun ti aṣẹ ijọba.

Oladamọran gomina ipinlẹ Ondo ṣalaye pe ile iṣẹ bulọọku ti ko ba tẹle aṣẹ ijọba yoo di titi pa.