Yoruba traditon: Ohun tí Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sàtánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́ -Ejùgbọ̀nà ìlú Rẹ́mọ

Àkọlé fídíò, Ohun ti Yorùbá ń pè ní Èṣù yàtọ̀ sí Sátánì nítorí Èṣù ní iṣẹ́ rere lọ́wọ́

Ọpọlọpọ igba ni adapọ ati edeaiyede maa n waye lori Esu. Ta ni, bawo lo ṣe jẹ ninu itan iṣẹdalẹ Yoruba ati pe ṣe lootọ ni pe idi iṣẹ buruku la ti maa n ri?

Edeaiyede yii lo mu ki ọpọ maa daa pe ni Satani, sugbọn awọn baba mọnimọni ṣalaye pe iyatọ pọnbele lo wa laarin Esu ti iṣẹṣe Yoruba ati Satani ti ọps awọn iwe ẹsin miran n fihan.

Ninu igbagbọ Yoruba, aṣeburuku ṣe rere ni Esu jẹ, bẹẹni ko si irumslẹ kankan nilẹ Yoruba ti kii fi ti Eṣu laalu ogiri oko ṣe.

BBC News Yoruba tọ awọn agba lọ lagbegbe Ijẹbu lati mu ẹkunrẹrẹ ims ati alaye lori Eṣu, ojuṣe rẹ laarin awọn igba irumọlẹ, ati ohun to faa ti ọps maa fi n pariwo iṣẹ Eṣu ni bi iṣẹlẹ buburu kan ba ti ọdọ wọn jade.