Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Àkọlé fídíò, Yoruba Nation: Ààrẹ ẹgbẹ VOR sọ pé kí ọmọ Yorùbá di ààrẹ Naijiria kọ́ ni ọ̀nà àbáyọ

Aarẹ ẹgbẹ Awọn Agba Yoruba , ti wọn n pe ni Voice of Reasoning Alagba Olufemi Adegoke, ti sọ pe ko si nkan tuntun ti ọmọ Yoruba yoo sẹ to ba de ipo aarẹ Naijiria.

O ni ṣebi ọmọ Yoruba ni aarẹ nigba kan, Olusegun Obasanjo, ti ko si ri nkan pataki kankan ṣe lati mu ki igbeaye rọrun fun awọn ọmọ Yoruba.

O sọ pe bakan naa ni Goodluck Jonathan to wa lati Gusu-Gusu Naijiria, ti oun naa ko ri nkan ṣe fun awọn eniyan rẹ.

Alagba Adegoke sọ pe ọpọlọpọ ọmọ Yoruba lo dibo fun Aarẹ Buhari nitori Yemi Osinbajo, ṣugbọn ẹnu Osinbajo paapaa ko tọrọ ninu iṣejọba.

“Nkan ti a nilo ni pe ka joko, ṣe atunsẹ ofin ọdun 1999, ka si dibo, ẹnikẹni to ba wọle naa ni.”

Lori ọrs ti oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples’ Democratic Party, PDP, Oloye Bode George sọ nipa erongba Bola Tinubu lati dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, Alagba Adegoke sọ pe otọ ọrọ ni George sọ pe ki wọn o lọ ọ yẹ ọpọlọ Bola Tinubu wo.

“Idi ni pe gbogbo nkan to n sẹlẹ si awọn ọmọ Yoruba lati ọjọ yii, ko si eyi ti Tinubu sọrọ le lori. Ẹnikẹni to ba ni ki Tinubu ṣe aarẹ, o yẹ ki wọn o yẹ ori ẹni naa wo.

Bakan naa lo sọrọ lori akitiyan Sunday Igboho. O ni lootọ akinkanju ni Igboho, ṣugbọn kii ṣe ilana kumọ ni wọn fi n ṣe ijijagbara.

Ni ti ẹgbẹ wọn, VOR, awọn ko faramọ iyapa kuro ni Naijiria, ṣugbọn nkan ti awọn n polongo ni pe ki wọn o pin awọn nkan to wa ni Naijiria dọgba-dọgba fun gbogbo ẹya.