Ondo state citizen killed in Jos: àwọn Fúlàní ìpínlẹ̀ Ondo tí wọ́n pa mọ̀lẹ́bí wọn ní Jos pariwo síta
Usman Tefiu, ẹgbọn ọkan lara awọn Fulani to fi ipinlẹ Ondo ṣe ibugbe ti awọn agbebọn Origwe, ni ariwa Jos, nipinlẹ Plateau pa lọjọ Satide, Maman Lawal, ti rọ ijọba lati yara lati mu awọn to ṣe ijamba ọun lati dena awọn ara ilu lati gbẹsan funra wọn.
Tefiu to ti padanu ẹsẹ rẹ mejeeji to si n fi ọpa rin lo sọ pe ohun ati baba ohun ti ko riran ni o nira fun lati gba iku Maman to padanu ẹmi rẹ lakoko to n pada sipinlẹ Ondo lati ipinlẹ Bauchi.
- Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ Èṣù táwọn èèyàn ń pariwo kò rí bẹ́ẹ̀, aṣe burúkú ṣe rere ni Èṣù
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
- A fẹ́ ta ọjà wa ló mú kí fíìmù oníhòhò ó pọ̀ lórí igbá - Rose Odika
- Ó di ìgbà tí àwọn olóṣèlú bá n fi nkan àbáláyé búra kí Naijiria tó le rójú - Ọba Ogboni Iwasẹ
- Ọ̀rọ̀ òpònú tí kò mú ọgbọ́n wa ni pé kí ọmọ Yorùbá du ipò tàbí di ààrẹ ní 2023 - Ẹgbẹ́ Àgbà Yorùbá
Darandaran miran, Abdulai Shu'aibu eni ti'o padanu ọmọ re sọpe ohun gbogbo ko sebẹ sẹnu're mọ lẹyin ti wọn sọ iroyin ibanujẹ nipa iku ọmọ re fun, ti o si kesi ijoba lati fi panpẹ ofin mu awọn ti o sekupa ọmọ rẹ.
Nibi ipade alaafia ti won se nilu Ibaram-Akoko, to wa ni ijọba ibilẹ Iwọ oorun-Ariwa Akoko, igbakeji gomina, Lucky Aiyedatiwa to ṣoju Akeredolu ti sọ pe ijọba ipinlẹ Ondo ati Plateau n sisẹ takun-takun pẹlu awon ẹsọ alaabo lati fi panpẹ mu awọn to sọsẹ naa.