Lionel Messi: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Lionel Messi lè gba ife ẹ̀yẹ Champions League fún PSG lẹ́ni ọdún 34?

Oríṣun àwòrán, Facebook/PSG
Ọpọ ololufẹ ere bọọlu lo ti sọrọ nipa igbesẹ Lionel Messi lati darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu PSG lati Barcelona.
Awọn kan ni asiko ti to fun ẹgbẹ agbabọọlu PSG lati gba ife ẹyẹ UEFA Champions League eleyii ti wọn ko tii gba ri ninu itan wọn.
Agbaọjẹ agbabọọlu orilẹede Brazil to ti fẹyin ti naa sọ pe oun n gbọ oorun Champiọns League ni PSG bayii lẹyin ti Messi darapọ mọ wọn tan.
- Ó tó gẹ́! Ààrẹ Rwanda tutọ́ sókè fojú gbàá lórí ìfìdírẹmi Arsenal
- Ìkáyàsókè ní Ife, Modakẹ̀kẹ̀ lẹ́yìn tàwọn kan pa ọmọ Modakeke márùn ún
- Gómìnà Osun, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ sókè lórí wàhàlà tó bẹ́ sílẹ̀ láàrín Ife àti Modakeke lọ́jọ́ Ẹtì
- Ààrẹ tẹ́lẹ̀,GEJ, Atiku Abubakar,Fayemi ati àwọn mìíràn rèé tó péjú síbi ìgbéyàwó Yusuf Buhari
- Mercy Aigbe kò le rìn torí ìjàmbá tó ní
- Ọlọ́pàá mú afurasí tó pa oniṣowo ẹrọ igbowo POS kan, wọ́n ni àbọ̀dé ìgbẹ́jọ́ Sunday Igboho lọwọ́ tẹ̀ẹ́
- Àwọn jàǹdùkú sọ àjọ̀dún Amole di 'ọdún olè jíjà' nílùú Akure
Ronadinho to ti figba kan ri gbabọọlu fun PSG ati Barcelona sọ pe ohun iwuri lo jẹ foun pe oun ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu mejeeji.
O ni ife ẹyẹ UEFA Champions League ko jina mọ si PSG pẹlu Messi atawọn agbabọọlu mii bi Sergio Ramos ti wọn ṣẹṣẹ ra.
Messi mi ilẹ titi nigba to darapọ mọ PSG tan.
Niṣe lero pejọ biba si papa isẹre Parc des Princes nibi ti ẹgbẹ agbabọọlu PSG ti fi Messi han fun gbogbo aye.
Nọmba 30 lo wa lara jẹsi ti Messi yoo maa wọ ni ẹgbẹ agbabọọlu naa.
Ẹwẹ, gbajugbaja oniroyin to tun jẹ ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal, Piers Morgan ni PSG ko le padanu lori owo oṣu gọbọi ti Messi yoo maa gba.
Morgan ni PSG yoo ri owo wọn pada laarin oṣu diẹ lati ara jẹsi rẹ ti wọn ba ta.
Oniroyin Morgan ni witi witi lawọn ololufẹ ere bọọlu n ra aṣọ Messi, eleyii ti yoo si tẹsiwaju bẹẹ.













