Brentford vs Arsenal highlights: Fòní kú fọ̀la dìde Arsenal dojuú ṣú Ààrẹ Rwanda, ó ní kí wọ́n wá nǹkan ṣe

Aworan Aarẹ Kagame ati agbabọọlu Arsenal David Luiz

Oríṣun àwòrán, Facebook/PresidentPaulKagame

Ifidirẹmi ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal to ti wa fẹ di lemọ-lemọ yi ti n mu iriwisi ọtọọtọ wa.

Nibi ti ọrọ yi de duro bayii, awọn ọmọ ẹgbẹ naa loriṣiriṣi lo ti n fi ibinu han si bi wọn ti ṣe n foju ẹgbẹ wọn gbole ni gbogbo igba.

Ọrọ taa n wi yi ta ba ara ile o ta ba ra oko.

Koda o fọwọ kan aarẹ orileede Rwanda, Paul Kagame lẹmi debi pe o fi aidunnu rẹ han si bi ẹgbẹ naa ṣe fidi rẹmi lọjọ kini saa bọọlu tuntun Premiership ilẹ Gẹẹsi.

Kagame jẹ alatilẹyin ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti orileede rẹ naa si n ṣagbatẹru ẹgbẹ naa.

Ẹgbẹ agbabọọlu Brentford to ṣeṣe n darapọ mọ liigi Premiership lẹyin ọdun mẹrinlelaadọrin lo da bantẹ iya goolu meji si odo fun Arsenal.

Aworan aarẹ Kagame ati ami idanimọ Arsenal

Lati igba ti Arsenal ati Rwanda ti jọ dowo pọ, ibaṣepọ naa ko ti ṣebi ẹni so eso rere lori papa.

Lọdun 2018 ni Rwanda ṣagbatẹru Arsena pẹlu owo to wọ miliọnu mejilelogoji dọla ti wọn si kọ ''Visit Rwanda'' si ara jẹsi Arsenal.

Lẹyin ifẹsẹwọnsẹ to waye lọjọ Ẹti, Kagame kọ soju opo Twitter rẹ pe awọn ko le faramọ aimọṣe ẹgbẹ yi.

Aworan agbaboolu Arsenal t

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Orileede Rwanda jẹ alatilẹyin fun ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal

O ni ẹgbẹ agbabọọlu ni lati mu ọkan pe awọn yoo maa bori ni gbogbo igba ni.

Aarẹ Kagame ni o yẹ ki wọn ṣe agbekalẹ ilana ti yoo so eso ati pe ko tọ ki awọn alatilẹyin ẹgbẹ maa fara da aṣiṣe ni gbogbo igba.