Ìdúnnú Arsenal padà síkùn, nígbà tí Watford yí wọn lágbo dà síná

Pierre-Emerick Aubameyang

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pierre-Emerick Aubameyang jẹ bọ́ọ̀lù méjì kí wọ́n tó lọ ìsimi ààrin àsìkò

Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Watford padà gbá ọ̀mì 2-2 pẹ̀lú Arsenal lẹ́yìn tí Gunners kọ́kọ́ síwájú wọn pẹ̀lú àmì ayò méjì.

Wọ́n jẹ padà lẹ́yìn tí Tom Cleverley gba bọ́ọ̀lù lọ́wọ́ọ Sokratis Papastathopoulos tó gbá ẹ̀yìn fún Arsenal saájúu kí Roberto Pereyra tó gbá pẹnáritì wọlé ní ìṣẹ́jú mọ́kànlélọ́gọ́rin sí ìbẹ̀rẹ̀ eré.

Pierre-Emerick Aubameyang lọ́ kọ́kọ́ bá Arsenal jẹ nígbà tó gba bọ́ọ̀lù tí Sead Kolasinac gbá síi kótó gbá bọ́ọ̀lù kọjáa Ben Foster tó bá Watford múlé.

Arsenal jẹ góólù kejì nígbà tí Aubemeyang gbá bọ́ọ̀lù wọ àwọ̀n ní ẹlẹ́ẹ̀kejì, ṣùgbọ́n Watford bẹ̀rẹ̀ sí jà fita-fita nígbà tí wọ́n padà wọ̀ oríi pápá láti ìsimi àsìkò ní wájú àwọn alátìlẹyìn wọn tí wọ́n wà nílé.

Àwọn Hornets ò bá na Arsenal pẹ̀lú àmì ayò 3-2, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni bọ́ọ̀lù tí Gerard Deulofeu gbá fi gba ẹ̀gbẹ́ ojú ilé Arsenal kọjá.