Tammy Abraham lewaju,Tomori tẹle bí Chelsea ṣe dáná sun Wolves mọ́lé

Tammy Abraham

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi wọn ba gun ẹsin ninu awọn alatilẹyin Chelsea bayi, geree ni yoo ma lọ pẹlu bi wọn ti ṣe fi goolu marun un ṣagba meji Wolves ninu ifẹsẹwọnṣẹ to waye ninu idije Premiership.

Bi a ba si ni pe ki a pe ori awọn akọni to sọ idunnu yi d'ayọ wa, orukọ awọn agbabọọlu meji ti wọn ni ẹjẹ Naijiria lara la o ma pe.

Orukọ Tammy Abraham ati Fikayọ Tomori wa lara awọn to jẹ goolu mẹrin ninu marun un ti Chelse fi pegede ọhun.

Tammy Abraham jẹ mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ naa, eleyi to mu ki iye goolu rẹ to ti jẹ ni Premiership di meje ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta to gba kọja.

Ọmọ ọdun mọkanlelogun pere ni Tammy Abraham ti o si jẹ agbabọọlu Chelsea to kere ju lọ lati jẹ goolu mẹta ninu ifẹsẹwọnsẹ kan.