Afghanistan Crisis: Ikọ̀ Taliban ti ń jó, wọ́n tún lọ ibùdó ìgbafẹ́ láti ṣeré yàtọ̀ sí ti tẹ́lẹ̀

An ogun Taliban

Idi ni pe ọpọ fidio lo ti jade sita bayii to n se afihan awọn Taliban ni ibudo igbafẹ, ti wọn jo, ti wọn si n sere lorisirisi.

Ọpọ eeyan to wo awọn fidio yii lo n ya lẹnu pe se awọn ikọ Taliban to gba ijọba ni bi ogun ọdun lorilẹede Afghanistan ree abi awọn miran.

Awọn ikọ Taliban yii si ni awọn eeyan mọ bii agbebọn, ti wọn kii si rẹrin tabi jo, tabi fi aaye silẹ fun ere idaraya sise.

Koda, wọn ni ibẹru to bẹẹ gẹ debi pe awọn obinrin maa n gbọn niwaju wọn ni, ti ibọn kii si ja lara wọn.

Fidio mẹrin to wa lu sori ayelujara ni Ọjọbọ lo se afihan awọn ọmọde ati obinrin ti wọn pejọ nibudo igbafẹ kan lati wo awọn ikọ agbebọn naa.

Bakan naa ni fidio yii tun se afihan awọn ikọ Taliban ti wọn n fo soke-silẹ lori ohun eelo isere kan ti wọn pe ni Bouncing Castle.

Awọn ọmọde si ni wọn mọ, to maa n fi ohun isere naa dara ya.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Update: Igboho ti sọ ohun tó fẹ́ kí a ṣe tí ọ̀rs bá bẹ́yìn yọ- Saheed Yusuf

Amọ ninu fidio yii ni a ti ri awọn ọmọ ẹgbẹ Taliban naa, ti wọn si lawani ti wọn we sori kalẹ, lọna ati mu ki ere sise naa rọrun fun wọn.

Awọn ikọ Taliban naa sa n rẹrin, rẹrin titi ninu fidio naa ni, lai fajuro.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Fidio kẹta lo se afihan ikọ Taliban, ti wọn tun n wa kẹkẹ ere idaraya fun irin, ti wọn n pe ni Tred Mill, ti wọn si n rin lori rẹ.

Amọ wn ko si lawani wọn lori ninu fidio kẹta naa, boya nitori pe wọn ko bẹru pe o le tu tu lasiko ti wọn n rin naa.

Lẹyin ere idaraya yii ni awọn ikọ Taliban naa gba ile nla kan lọ, tii se ile ijọba ilẹ Afghanistan.

Àkọlé fídíò, Ẹwa Agọnyin jẹ aayo ounjẹ Badagry