Seyi Makinde: Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo ní òun jẹ dòdò báwọn nkan ṣe ń pè òun ní ''audio governor''

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde sọ pe ipakọ o gbọ suti, ori ẹlẹgan an lo daru lọrọ awọn to n pe oun ni ''audio governor.''

Makinde sọrọ yii nigba to n ṣe ifilọlẹ awọn kọmiṣọnna meje to yan sipo pada lọjọ Ẹti niluu Ibadan.

Gomina ipinlẹ Oyo ṣalaye ninu atẹjade kan ti akọwe iroyin rẹ, Taiwo Adisa fi sita pe awọn alako ijọba oun ko ni ṣai ri ariwisi kan tabi omiran nipa iṣejọba oun.

Amọ, Makinde sọ pe ijọba oun ko ni kaarẹ nipa pipese ohun amaye dẹrun fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.

''Mo ranti ni bii ọdun kan sẹyin pe awọn kan maa n sọ pe ''audio'' ni gbogbo iṣẹ ti a sọ pe a n ṣe nipinlẹ Oyo.

Ṣugbọn to jẹ pe ''audio'' lawọn iṣẹ iṣẹ ti a nṣe ni tootọọ, o tumọ si pe awọn eeyan n ri ẹri ohun ti a n ṣe.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Nigba ti a ba ṣetan ni wọn yoo mọ pe ọpọn ti tun siwaju ninu eto iṣejọba nipinlẹ Oyo.

Laipẹ yii ti mo n ba gomina kan sọrọ lo sọ fun mi pe, ''audio governor'' ni wọn n kọkọ pe mi.

Ṣugbọn ni bayii wọn ti n ri ohun ti a n ṣe, wọn n wa beere bo ya a maa le tẹsiwaju lati maa ṣe ohun ti n ṣe bayii.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

A o ti jẹ owo oṣu awọn oṣiṣẹ ati owo ifẹhinti fun ọdun meji, awawi naa ni wọn yoo maa wa titi ti wọn ko fi ni ri nkan kan sọ mọ,'' Makinde lo ṣalaye bẹẹ.

Makinde rọ awọn kọmiṣọnna to ṣẹṣẹ yan sipo lati tubọ ṣiṣẹ takun takun ki awọn eeyan ipinlẹ Oyo le ri ere ijọba oun jẹ.

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

Gomina ni asiko ti ko si adari gidi ni ipinlẹ Oyo ti lọ.

O ni gbogbo kọmiṣọnna lo ni ipa pataki lati ko ninu titu ọkọ ipinlẹ Oyo lọna tawọn araalu yoo fi gbadun ijọba.

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde