Olu of Warri Emiko coronation: Ogiame Atuwatse III yí gbogbo ègún to ba ipò rẹ̀ gẹgẹ bi ọba rin

Olu ti Warri tuntun ti kede oye tuntun meji ti wọn yoo ma jẹ lasiko ijọba rẹ lasiko ti wọn gbe ọpa aṣẹ le lọwọ loni gẹgẹ bi Ogiame Atunwatse kẹta.
Ogiame Atuwaste kẹta ti a mọ si Omoba Utieyinoritsetsola Emiko tẹlẹ ti gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Olu ẹlẹkọkanlelogun.
Ní bayìí Olu ti Warri to jẹ Oba fun gbogbo ọmọ Itṣekiri ni ipinlẹ Delta ti yí orúkọ oye iyawo rẹ pada.
Lẹyin to gba ọpa aṣẹ tan lo paarọ orukọ tuntun ti wọn yoo maa pe iyawo rẹ
Orukọ oye tuntun fun iyawo rẹ ni Omooba Ivie Emiko Olori si Atuwatse kẹta.
Wo awọn nnkan tuntun miiran ti Olu ti Warri sọ lasiko Iwuye rẹ:
Ogiame Atuwatse Keta yi awọn egun kan pada
Ogiame Atuiwatse kẹta yi egun ti Olu Erejuwa keji ati oba Akenzua gbe lori apere lasiko ti wọn kuro.
Bákan náà lo gbadura idariji ati fun iwosan fun ijọba apapọ orilede Naijiria ti o lo lati huwa ika naa
" Mo pasẹ irọrun, ilọsiwaju, iṣe rere lori gbogbo ilẹ "
" A n pasẹ nitori alabukun fun ni ilẹ Itsekiri, Ibunkun ni fun orilede Naijiria, eyi jẹ ọkan lara nnkan ti OLu Warri gba ladura

Ogiame Atuwatse kẹta fun iya ré ni oye tuntun
Olu ti Warri fi oye tuntun da awọn obinrin meji to ṣe pataki laye rẹ lọla, iya rẹ ati iyawo rẹ.
Iroyin sọ pe Olu ti Warri ẹlẹkọkalelogun yii ni Olu akọkọ ti iya ré wa laye lasiko to je ọba ti yoo si ri iwujye ọmọ rẹ.
Iya Olu yii naa joko lati ri ayẹyẹ iwuye ọmọ rẹ ti ko si ṣẹlẹ ri lati bi sẹnturi meji ṣẹyin.
O yi oye rẹ pada lati olori Atuwaste keji si Iyowu Atuwatse keji.
Olu ti Warri jẹ oba alade onipo kini, oun si ni Oba lori gbogbo ọmọ Itṣekiri nile ati lẹyin odi.
Gbogbo awọn lọba lọba pẹlu awọn borokini eniyan lo peju sibi ayẹyẹ iwuye naa to waye ni Ilu Warri ipinlé Delta lọjọ Satide, to fi mọ Ooni ti Ife.
- Òjò àrọ̀rọ̀dá gbẹ̀mí èèyàn mẹ́ta ní Oshogbo,ọ̀pọ̀ dúkìá ṣòfò
- Àwọn ìlúmọ̀ọ́ká Mẹ́wàá to kú nínú oṣù keje odun 2021
- "Ẹ yé fún àwọn ọkọ yín lọ́yàn mu mọ́, àwọn ọmọ ló lọyàn"
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ààrẹ Naijiria tẹ́lẹ̀, Umar Musa Yar'Adua sí ẹ̀wọ̀n nítorí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- Ìgbà díẹ̀ ló kù kí Secondus parí sáà rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fi ara dà á títí yóò fi lọ PDP
- Ìyàwò fi ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀ fún ọdún mẹ́rin, ìgbèyàwò tú ká
Itan Warri ni ranpẹ
Oba Warri tabi Oba Iwere lati ọdun (1480 - 1848) ti wa lati aye awọn ijọba amunisin .
Olu tabi Ogiame(Oba) Warri lo jẹ oba lori gbogbo awọn ara Itsekiri ni ipinlẹ Delta ni Naijiria.
Gẹgẹ bi itan Bini ati ti Itsekiri Olu Ginuwa to jẹ ọmọoba Bini lo ṣe agbeka;e Warri ni ọdun 1480.
Ni ọdun 1997, labẹ ijọba Sanni Abacha ni wọn ṣe idasilẹ ijọba ibilẹ Warri South-West ti wọn si fi oluulu rẹ si Ogidigben to jẹ ilu àwọn Itsekiri ni Warri
















