Ilé ẹjọ́ tú ìgbèyàwò ká lẹ́yìn tí ìyàwò fi ìbálòpọ̀ dun ọkọ rẹ̀ fún ọdún mẹ́rin

Divorce

Oríṣun àwòrán, Tumisu

Ile ẹjọ kan niluu Eko ti tu igbeyawo tọkọtaya kan ka lẹyin ti ọkọ, Eric Frank, fẹsun kan iyawo rẹ pe o fi ibalopọ dun oun fun ọdun mẹrin gbako.

Nigba to n ṣedajọ naa, Adajọ Adeniyi Koledoye sọ pe oun gbe igbesẹ lati tu igbeyawo naa niwọn igba ti ọkọ ti sọ pe ituka ni oun n fẹ lẹyin ti gbogbo igbiyanju rẹ lati pari ija laarin oun ati aya rẹ ja si pabo.

O ni "Ile ẹjọ yii ti tu igbeyawo laarin ọgbẹni Eric ati Ibeawuchi Frank ka lonii."

"Nitori naa, ẹyin mejeji kii ṣe ọkọ ati aya mọ lati oni lọ."

Lẹyin naa lo ni awọn mejeji le maa lọ lọtọọtọ lai si wahala kanka laarin wọn.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap

Ẹwẹ, adajọ Koledoye paṣẹ pe ki ọgbẹni Frank san ₦150,000 owo ituka fun aya rẹ ọhun, bẹẹ lo tun ni ko fun obinrin naa ni ₦200,000 lati fi gba ile tuntun ti yoo maa gbe.

Ṣaaju ni ọkunrni ọhun ti kọkọ ke si ile ẹjọ naa lati tu igbeyawo naa ka lori ẹsun pe o fi ẹtọ oun ninu ile dun oun.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho: Timi Orokoya ní orin Iléyá tí òun kọ lọ́dún 28 sẹ́yìn, ló padà wá ṣẹ báyìí

Ẹni ọdun mẹrindinlọgọta naa ni "Iyawo mi n fi ẹtọ mi ninu iyara dun mi, o tun sọ pe oun yoo pa mi ti oun yoo si jogun awọn dukia mi."

O tẹsiwaju pe "Iyawo mi gba ₦420,000 lọwọ ayalegbe mi lai sọ fun mi, ko tun ṣalaye bo ṣe na owo naa."

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

Ọgbẹni naa tun fẹsun kan iyawo rẹ pe o maa n ya ile awọn oni yẹmiwo ati oriṣiriṣi wolii ti oun ko si nifẹ si.

Lẹyin atotonu awọn mejeji, ile ẹjọ ni ki wọn maa lọ lọtọọtọ.

Àkọlé fídíò, Osun Osogbo: Ọdọọdún ni Àtáója ń gbàlejò gbogbo arugbá lásìkò ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo