Sunday Igboho sues federal government: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ pé ìjọba kò gbọdọ̀ yọ Igboho lẹ́nu di ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ míràn

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, SUNDAY ADEYEMO IGBOHO FOUNDATION/CFACEBOOK

Igbẹjọ tun waye lonii ni ile ẹjọ giga ti ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni agbegbe Ring-Road nilu Ibadan, lori ẹjọ ti ajijagbara Yoruba Nation, Sunday Igboho pe tako ijọba Naijiria.

Akọroyin BBC jabọ pe botilẹ jẹ pe awọn agbẹjọro Sunday Igboho wa nile ẹjọ, aṣoju ijọba ko yọju.

Agbẹjọro fun olupẹjọ, Yomi Alliyu SAN sọ fun BBC pe ile ẹjọ ti paṣẹ pe ki aabo wa fun Sunday Igboho.

"Ile ẹjọ ti fun ni anfaani bayii pe o le rin laarin ilu laijẹ pe oṣiṣẹ eleto aabo mu, tabi kọẹu oun, ile ati dukia rẹ.

Bakan naa ni ile ẹjọ sọ pe wọn ko gbọdọ lọ si ile rẹ titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ti igbẹjọ miran yoo tun waye.

O ni owo ọna meji ni awọn n beere lọwọ ijọba fun Sunday Igboho.

Ikinni jẹ ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira, ikeji naa jẹ ẹẹdẹgbẹta biliọnu Naira.

Àkọlé fídíò, Esabod, Sunday Igboho: Kò burú bí Igboho ṣe wà lẹ́wọ̀n báyìí,ọ̀rọ̀ rẹ̀ dàbí i ti aláboyún

Ikọọkan wọn wa fun awọn dukia to ṣe e fi oju ri ti ajọ DSS bajẹ nile Sunday Igboho, ikeji si wa fun ẹtọ rẹ ti wọn tẹ mọlẹ, to fi mọ awọn eeyan ti wọn pa.

Lori boya ijọba Naijiria yoo tẹle aṣẹ ile ẹjọ, Yomi Alliyu sọ pe ijọba ni lati tẹle aṣẹ ile ẹjọ, nitori pe ijiya wa fun ẹnikẹni ti ko ba tẹle iru aṣẹ bẹ ẹ.

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday igboho

Ìgbẹ́jọ́ yóò wáyé lórí N5bn tí Sunday Igboho pè tako DSS àti ìjọba Naijiria:

Oni, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹjọ, ọdun 2021 ni ile ẹjọ giga kan to jẹ ti ijọba ipinlẹ Oyo, nilu Ibadan, yoo tun gbọ ẹjọ ti ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Adeyemo 'Igboho' pe ijọba Naijiria.

Sunday Igboho pe ijọba Naijiria lẹjọ lati beere fun biliọnu marun-un Naira gẹgẹ bi owo lati tu u loju fun awọn dukia rẹ ti awọn oṣiṣẹ ajọ DSS ba jẹ lasiko ti wọn kọlu ile rẹ nilu Ibadan lọjọ kinni, oṣu Keje.

Bakan naa ni Igboho, nipasẹ agbẹjọro rẹ, Oloye Yomi Alliyu (SAN) tun n fẹ ki ile ẹjọ fi ofin de Agbẹjọro Agba Naijiria, ajọ DSS, ati awọn oṣiṣẹ alaabo yooku, lati má mu u tabi fi ẹtọ rẹ dun un.

Àkọlé fídíò, Igi Ọ̀pẹ abàmì tó dá ní orí 42 l'Ekiti rèé o, 'bí mo ṣe ríi l'orí mi ń dìde fììì'

Eyi jẹ ẹbẹ tuntun ti Igboho fẹ ẹ gbe lọ siwaju ile ẹjọ, ko to o di pe igbẹjọ bẹrẹ lori ti owo itanran to fẹ ẹ gba lọwọ ijọba.

Sunday Igboho wa ni ọgba ẹwọn lọwọlọwọ ni orilẹ-ede Benin Republic.