Bode George: Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sọ ìdí tí ẹgbẹ́ náà fi kùnà láti wọlé ìbò gómìnà l'Eko

Bode G

Oríṣun àwòrán, @TheTrentOnline

Eekan ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Eko, Oloye Bode George ti ṣalaye ohun to faa ti ẹgbẹ naa ko ṣe tii wọle ibo gomina lati ọdun 1999 di akoko yii.

Oloye George ṣalaye minu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin Punch pe awarada kẹrikẹri ni ọrọ eto idibo nipinlẹ Eko.

Bode George ni ọwọ lasan lawọn eeyan fi n ko iwe idibo kaakiri ibudo idibo l'Eko, eleyii to ni ko dara rara.

''A ti n sọ tipẹ pe ki a maa lo ẹrọ kọmputa fun eto idibo wa, ọpọ ko fẹ gbọ.

Eeyan kan ti ji owo ipinlẹ Eko debi wi pe o ti lowo ju orilẹede Naijiria gan an lọ, ba wo ni PDP ṣe fẹ bori ninu eto idibo bayẹn?

Ẹ wo eto idibo ijọba ibilẹ to lọ nipinlẹ Eko, o buru debi pe awọn araalu ko tilẹ jade dibo nitori wọn ti sọ ireti nu.

O rọrun fun wọn lati ra ibo pẹlu ọpọ eeyan ti ebi n pa niluu ti inu wọn ko dun.

Àkọlé fídíò, Oba Gbolahan Timson shomolu: Obasanjo ti jẹ́wọ́ pé 'Mistake' ni Buhari ṣùgbọ́n...

Mi o mọ ibi ti orilẹede yii n lọ gan an, a ni lati ba awọn to n ṣe ijọba sọ otitọ ọrọ.

Kilode gan an ti a ko fi le maa lo ẹrọ kọmputa dibo ati gbe esi idibo jade ki awọn tawọn araalu dibo yan le maa de ipo?

Àkọlé fídíò, Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde

A o ti bẹrẹ ohun kankan bayii o, a ṣi n ṣe ere lọwọ pẹlu bi eto idibo wa ṣe ri lọwọ yii,'' Oloye George ṣalaye.

Igbakeji alaga gbogbo ẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ rọ Aarẹ Muhammadu Buhari pe ki o faye gba atunto Naijiria bi eto idibo 2023 ti n kan ilẹkun.

Àkọlé fídíò, Olawale Dada: Igbá bárà kọ́ ló kàn, àwa náà n ṣoríire láyé pẹ̀lú ìpèníjà 'Cerebral Palsy'

O ni eyi nikan lo le mu ki alaafia jọba lorilẹede Naijiria, ''irọ lasan an ni gbogbo awọn to n fo kiri bi ẹyẹ pe awọn lo maa jẹ aarẹ lọdun 2023.

Pẹlu eto idibo to wa nilẹ yii, eeru ni a ba nibẹ, eto idibo ti a n lo yii ko lootọọ, ẹ jẹ ka gbiyanju omiran wo,'' Oloye George lo sọ bẹẹ.

Àkọlé fídíò, Taye Osinowo Olaosebikafi Iyabo Ojo, Mide Martins, Jaye Kuti, Afeez Owo àtàwọn míì dárà ap