Bobrisky: Ìnira iṣẹ́ abẹ ìdí kìí ṣe kèrémí, ẹyin ti Elédùà fún ni ìkébè, ooré ńla ni

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Gbajúgbajà ọkunrin to n wọ asọ obìnrin, Idris Okunneye tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Bobrisky, ló ṣe isẹ abẹ ìdí rẹ̀ láìpẹ́ yìí, láti le mú kó tún rẹwà sí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.
Láti àsìkò tó si tí ṣe isẹ abẹ́ yìí, náà sì ló ti bẹ̀rẹ̀ sí ni sọ ìrírí rẹ̀ nípa iṣẹ́ abẹ náà.
Lójú òpó Instagram rẹ̀ ló ti ṣàlàyé pé, gbogbo àwọn ènìyàn tí Elédùà fún ni ìkébè lọ́fẹ̀ẹ́, kò mọ oore tí ó ṣe fún wọ́n.
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
- Bí àwọn ọ̀tá mi bá jẹ ilá àti ẹ̀bà tán, itẹ́ òkú ní wọn yóò ti fọwọ́ - Bobrisky
- Mò máa ń fọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìyá mi, ni ìṣe àwọn obìnrin fi wù mí - Bobrisky
- Kí ló pa Bobrisky àti Olorì Aláàfin Oyo pọ̀?
- Ìjà ìgboro rèé o, ṣe bí ọkùnrin ni Bobrisky ṣe bá ọkùnrin ẹgbẹ́ rẹ̀ jà ní?
Ó wa sọ gbogbo nǹkan ti ojú rẹ̀ rí lásíkò iṣẹ́ abẹ̀ náà, gẹ́gẹ́ bí ó ṣe kọ́ sójú òpó rẹ̀.
O ni "Ẹ má jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ yín parọ́ fún yín pé iṣẹ́ abẹ̀ ìkébè kò nira, irọ́ ní.
Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mí tó gbà mí ní ìyànjú láti ló ṣe isẹ abẹ idi, ni mo ṣì ń ṣépè fún lọ́wọ́lọ́wọ́ fun"
"Ìnira rẹ̀ pọ̀ gidigidi, ẹ̀yin ti elédúà fún ni ìkébè láti ọ̀run wa, ẹ̀ ko lé mọyi"
Bobrisky ni bí ènìyàn bá ṣe iṣẹ́ abẹ ikébè, ẹni náà yóò kúrò lórí ayélujára fún bi oṣù kan gbáko, kí nǹkan mííràn má bá wọ fún.
Ìlúmọ̀ọ̀ká náà wa rọ gbogbo àwọn to n kan òun lójú láti gbé fótó idi tuntun jáde, pe ki wọ́n lọ ni sùúrù,
"Sé ẹ mọ ibí ti wọ́n ti fún mi ni abẹ́rẹ́ ni, Inú ọ̀pá ẹ̀yìn mí ni wọ́n gún lábẹ́rẹ́, títí di àsìkò yìí ọ̀pá ẹ̀yìn mi ṣì ń dùn mí gidigidi, kí ẹnikẹ́ni maa kan mi lójú o ẹ jọ̀wọ́"

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Ó fi kun pé lẹ́yìn irú iṣẹ́ abẹ báyìí, ó se pàtàkì láti tọ́jú ara ẹni, nítorí ọ̀rọ̀ iṣẹ́ abẹ ìkébè kọjá kí ènìyàn máa fi aworan bí ènìyàn ṣe rẹ̀wà tó hàn lórí ayélujára.
"Má jẹ́ kí ẹni kankan tàn ọ́ sínú pé, iṣẹ́ abẹ̀ náà rọrùn."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Jide Kosoko, tí mo bá tú àṣírí rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ yóò dọwọ́ bojú - Nkechi Blessing yarí
- Mo dẹ́kun àdúrà gbígbà lẹ́yìn ikú Ajimobi - Florence aya olóògbé
- Oríire dé! Aláànú kan fún Kemisola ní ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ dé fásitì
- Omo Borty sọ̀rọ̀ sókè lórí ìbáṣepọ̀ rẹ̀ àti Dino Melaye
- Òǹyẹ̀ kò lè yẹ ìwọ́de Yoruba Nation l‘Eko, mò ń bọ̀ níbẹ̀ - Sunday Igboho
- Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Bákan náà ló tún fi kun pé, ara òun ti n yá, òun sì ti le jòkó sórí ìrọ̀rí báyìí yàtọ̀ sí bi òun ṣe má n fi àyà sùn tẹ́lẹ̀.
Nínú fótò túntun tó gbé sójú òpó Instagram rẹ̀ ló tí fí bí o ṣe rí nísìnyìí lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ abẹ̀ ìkébè.



















