Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọ̀kan lára àwọn afurasí tó ṣekúpa DPO Bako

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police Command
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti tẹ ọkan lara awọn afurasi to ṣekupa SP DPO Bako Angbashim lagbegbe Ahoada nipinlẹ Rivers.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe-Koko ló fìdí ọrọ yii mulẹ.
SP Iringe-Koko ṣalaye pe ọjọ Aje ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹsan an yìí ni ọwọ tẹ afurasi naa nibi t'awọn kan ti sọ taya sí lọrun ti wọn si fẹ danae sùn un.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni awọn agbofinro lo doola ẹmi rẹ ti wọn sí jọwọ rẹ fawọn ẹka to n tọ pinpin ìwà ọdaran lati tẹsiwaju iṣẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.
Iringe-Koko ni ileeṣẹ ọlọpaa n gbiyanju lati mu 2-Baba to jẹ olori awọn janduku naa at'awọn ọdaran mii nipa ijẹwọ afurasi ti ọwọ tẹ.
Laipẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa fi aworan afurasi kan hàn lori iṣekupa ọga ọlọpaa naa.
Ijọba ipinlẹ Rivers naa gbe ọgọrun ùn miliọnu silẹ fun ẹnikẹni to ba le ri ẹni to pa SP Bako Angbashim.
Laipẹ yìí ni gomina ipinlẹ Rivers, Similaye Fubara kede pe ijọba n wa Gift David Okpara Okpolowu ti inagijẹ rẹ n jẹ 2-Baba at'awọn iṣọmọgbe rẹ lori iṣekupa DPO SP Bako Angbashim to jẹ ọga ọlọpaa ni Ahoada nipinlẹ Rivers.
Afurasi ti ọwọ tẹ jẹwọ pe oun lo ṣaaju awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun "Iceland cult" lọ si ibi t'awọn ti gẹgun de ọga ọlọpaa naa ki wọn to ṣeku pa a.
Iroyin ti a gbọ n'ipe DP Bako at'awọn ọlọpaa mii n bọ lati ibi ti wọn ti lọ ṣiṣẹ kan l'awọn afurasi 2-Baba at'awọn iṣọmọgbe rẹ ti kọlu wọn.

Oríṣun àwòrán, Rivers State Police Command
Gomina Fubara ni 2-Baba at'awọn akẹgbẹ rẹ lo yìnbọn pa DPO Bako.
Iwadii ileeṣẹ ọlọpaa tun fidii rẹ mulẹ pe 2-Baba at'awọn iṣọmọgbe rẹ lo wa nidi ọrọ naa, ati pe agbegbe Ahoada yii gan an ni wọn wa ti wọn ti huwa ọdaran to fi mọ ijinigbe pa owo ni ijọba ibilẹ Ila oorun Ahoada nipinlẹ Rivers.
Iku DPO Bako sí n ṣe ọpọ eeyan ni kayeefi tori wọn mọ ọga ọlọpaa naa gẹgẹ bii akọni ninu iṣẹ ọlọpaa.
Ọwọ tẹ afurasi mẹfa

Oríṣun àwòrán, @RIVERSPOLICENG/X
Bi iṣẹ iwadii lori awọn to ṣekupa SP Bako ti n lọ lọwọ, awọn ọlọpaa ti mu afurasi mẹfa ti wọn niṣe pẹlu iku ọga ọlọpaa naa.
Eleyii waye lẹyin ti awọn ọlọpaa yabo inu igbo kan lawujọ Odiemudie nibi t'awọn janduku ti ṣekupa SP Bako.
Agbẹnusọ ọlọpaa sọ pe oku ọga ọlọpaa ọhun l'awọn lọ gbe ati pe awọn tun sinu igbo naa fun iwadii agbegbe Odiemudie.
Iringe-Koko ṣalaye pe yatọ sí afurasi mẹfa t'awọn mu, ileeṣẹ ọlọpaa ti ri ibọn atọwọrọ kan gba pẹlu oriṣiriiṣi ogun.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣe ifọrọwanilẹnuwo fawọn afurasi mẹfa ọhun.
Iringe-Koko fikun ọrọ rẹ pe ọpọ olugbe agbegbe naa lo ti sa kuro níbẹ latari gbogbo ohun to n ṣẹlẹ níbẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe DPO mi ti lọ rọpo SP Bako ni Ahoada nigba ti iwadii sí n lọ lori awọn to ṣekupa a.
SP Zuokumor Richard ni wọn gbe lọ sí àgbègbè naa.
Ta ni SP Bako ti wọn pa ni Ahoada?
SP Bako Angbashim wa lati ipinlẹ Nasarawa.
Oun ni DPO agbegbe Bori tẹlẹ nibi ti o ti ṣe iṣẹ takuntakun nipa kikọju ìjà s'awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to n ṣọṣẹ lagbegbe Ogoni nipinlẹ Rivers.
Lati ibẹ ni wọn ti gbe lọ si Ahoada lati lọ kọjú ija bakan naa s'awọn ẹlẹgbẹ okunkun to n ṣọṣẹ lagbegbe naa.















